ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” Payá
    Ilé Ìṣọ́—2012 | June 15
    • 9 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń wá ọ̀nà láti lóye ohun tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún. Ìwé Dáníẹ́lì 2:41 ṣàpèjúwe ẹsẹ̀ tó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ náà pé ó jẹ́ “ìjọba” kan ṣoṣo. Torí náà, amọ̀ náà dúró fún àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn yìí ni kò jẹ́ kó le bí irin gẹ́gẹ́ bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Bíbélì sọ pé amọ̀ náà jẹ́ “ọmọ aráyé,” tàbí àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù. (Dán. 2:43) Lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn máa ń dìde láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn nípasẹ̀ ìpolongo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn tó ń jà fún òmìnira. Àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù kò jẹ́ kí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà lè lo agbára tó le bí irin. Bákan náà, àwọn èròǹgbà tó ta ko ti ìjọba àti èsì ìbò tó sún mọ́ ti àwọn tí ìjọba bọ́ sí lọ́wọ́ kì í jẹ́ kí àwọn aṣáájú tó gbajúmọ̀ pàápàá lè lo àṣẹ tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ohun tí ìjọba wọn fẹ́ gbé ṣe. Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìjọba náà yóò ní agbára lápá kan, yóò sì jẹ́ èyí tí ó gbẹgẹ́ lápá kan.”—Dán. 2:42; 2 Tím. 3:1-3.

  • Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” Payá
    Ilé Ìṣọ́—2012 | June 15
    • 11 Ǹjẹ́ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà ní ìtumọ̀ pàtàkì kankan? Gbé èyí yẹ̀ wò: Nínú àwọn ìran míì, Dáníẹ́lì sọ àwọn iye kan pàtó, bí àpẹẹrẹ, ó sọ iye àwọn ìwo tó wà ní orí onírúurú àwọn ẹranko tó rí. Àwọn iye yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Dáníẹ́lì ń ṣàpèjúwe ère náà, kò sọ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀. Torí náà, iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí iye àwọn apá, ọwọ́, ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tí ère náà ní kò ti ṣe pàtàkì. Àmọ́ Dáníẹ́lì dìídì sọ pé ẹsẹ̀ ère náà jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. Nínú àpèjúwe tó ṣe, a lè parí èrò sí pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ni yóò máa ṣàkóso ayé nígbà tí “òkúta” tó dúró fún Ìjọba Ọlọ́run bá kọlu ẹsẹ̀ ère náà.—Dán. 2:45.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́