ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni ohun pàtàkì tí Bíbélì dá lé. Ìjọba yẹn ni Jèhófà máa lò láti sọ ayé di Párádísè pa dà. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ti ń ṣàkóso báyìí? Àwọn nǹkan wo ló ti ṣe? Àwọn nǹkan wo ló sì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ẹ̀kọ́ yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ méjì tó tẹ̀ lé e.

      1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba Ìjọba náà?

      Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run. Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba náà, àtọ̀run ló sì ti ń ṣàkóso. (Mátíù 4:17; Jòhánù 18:36) Bíbélì sọ pé Jésù “máa jẹ Ọba . . . títí láé.” (Lúùkù 1:32, 33) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa ṣàkóso gbogbo àwọn tó wà láyé.

      2. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?

      Jésù nìkan kọ́ ló máa dá ṣàkóso. Àwọn èèyàn látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè . . . máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.” (Ìfihàn 5:9, 10) Àwọn mélòó ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé, àìmọye èèyàn ló ti di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) péré lára wọn ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ka Ìfihàn 14:1-4.) Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù láyé sì máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.​—Sáàmù 37:29.

      3. Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

      Nígbà míì, a lè rí àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàkóso tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣohun tó dáa fáwọn aráàlú, àmọ́ agbára wọn kì í gbé e láti ṣe gbogbo ohun tó dáa tí wọ́n ní lọ́kàn. Tó bá yá, ẹlòmíì á rọ́pò wọn, onítọ̀hún sì lè má ní ire ará ìlú lọ́kàn. Àmọ́ ní ti Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kò sẹ́ni tó lè rọ́pò ẹ̀ tàbí tó lè gba ìjọba lọ́wọ́ ẹ̀. Ọlọ́run ti “gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Gbogbo ayé ni Jésù máa ṣàkóso, kò sì ní ṣojúsàájú. Kò mọ síbẹ̀ o, ó nífẹ̀ẹ́ wa, olóore ni, ìdájọ́ òdodo ló máa ń ṣe, ó sì máa kọ́ àwọn èèyàn pé káwọn náà nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, kí wọ́n máa ṣoore, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo.​—Ka Àìsáyà 11:9.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi dáa ju ìjọba èèyàn lọ.

      Jésù Kristi ń ṣàkóso ayé látorí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Àwọn tí wọ́n máa bá a ṣàkóso wà lórí ìjókòó lẹ́yìn rẹ̀. Ògo Jèhófà ń tàn yòò lẹ́yìn wọn.

      4. Ìjọba kan tó lágbára máa ṣàkóso gbogbo ayé

      Jésù lágbára ju gbogbo àwọn tó ti ṣàkóso láyé lọ. Ka Mátíù 28:18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló mú kí àṣẹ Jésù ju ti àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso lọ?

      Ní ti ìjọba èèyàn, tẹ́nì kan bá ṣàkóso lónìí, ẹlòmíì á gbà á lọ́la, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ti ní apá ibi tí àkóso ẹ̀ dé. Àmọ́ Ìjọba Ọlọ́run ńkọ́? Ka Dáníẹ́lì 7:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé Ìjọba Ọlọ́run ‘kò ní pa run’?

      • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé gbogbo ayé ni Ìjọba Ọlọ́run á máa ṣàkóso?

      5. Ìjọba èèyàn gbọ́dọ̀ dópin

      Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?​—Àyọlò (1:41)

      • Àkóbá wo ni ìjọba èèyàn ti ṣe fún aráyé?

      Ka Oníwàásù 8:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé o gbà pé ó yẹ kí Ìjọba Ọlọ́run rọ́pò ìjọba èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      6. Ọ̀rọ̀ wa yé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso

      Torí pé Jésù Ọba wa ti gbé ayé rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lè “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” (Hébérù 4:15) Bákan náà, “látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè” ni Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso.​—Ìfihàn 5:9.

      • Ṣé ọkàn ẹ balẹ̀ bó o ṣe mọ̀ pé Jésù àti gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Àwọn ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run ti ń yàn látìgbà àtijọ́ títí di òde òní. Inú gbogbo ẹ̀yà àti èdè ni Ọlọ́run ti yàn wọ́n.

      Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin látinú gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù

      7. Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ti ìjọba èèyàn lọ

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn òfin tí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-​11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run?a

      • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àwọn òfin yìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn òfin yìí lè yí pa dà?​—Wo ẹsẹ 11.

      Ọlọ́pàá kan dá mọ́tò dúró ní oríta kan táwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Àwọn èèyàn lọ́mọdé àti lágbá ń sọdá títì.

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Àmọ́ àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ṣàǹfààní gan-an ju ti ìjọba èèyàn lọ

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọ̀run, ó sì máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé.

      Kí lo rí kọ́?

      • Àwọn wo ló máa jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run?

      • Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

      • Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan ti Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ibi tí Jésù sọ pé Ìjọba Ọlọ́run wà.

      “Ṣé Inú Ọkàn Rẹ Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi gbogbo ọkàn wa tì lẹ́yìn dípò ìjọba èèyàn?

      Ìjọba Ọlọ́run Ni Wọ́n Fara Mọ́ (1:43)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí Jèhófà yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.

      “Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Kí ló mú kí obìnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìrẹ́jẹ kúrò láyé?

      “Mo Ti Wá Mọ Bí Àìṣẹ̀tọ́ Ṣe Máa Dópin” (Jí!, July-September, 2011)

      a A máa ṣàlàyé àwọn kan lára òfin yìí tá a bá dé Apá 3.

  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún Aráyé
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Láìpẹ́, ó máa tún ayé yìí ṣe. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run.

      1. Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba láyé?

      Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn burúkú run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. (Ìfihàn 16:14, 16) Tó bá dìgbà yẹn, ohun tó wà ní Sáàmù 37:10 máa ṣẹ láìkù síbì kan. Ó ní: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́.” Jésù máa lo Ìjọba Ọlọ́run láti mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba ní gbogbo ayé.​—Ka Àìsáyà 11:4.

      2. Báwo ni ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́?

      Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, “àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sáàmù 37:29) Fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá jẹ́ olódodo, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn! Àwọn èèyàn ò ní máa ṣàìsàn mọ́, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.

      3. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run?

      Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run, Jésù máa ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. Nígbà yẹn, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá a ṣàkóso á sọ gbogbo èèyàn tó wà láyé di pípé. Tí ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn bá fi máa parí, ayé á ti di Párádísè, àwọn èèyàn tó jẹ́ aláyọ̀ torí pé wọ́n ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu ló sì máa wà ní gbogbo ayé. Lẹ́yìn náà, Jésù máa dá àkóso pa dà fún Jèhófà Bàbá rẹ̀. ‘Orúkọ Jèhófà á wá di mímọ́’ lọ́nà tó ga jù lọ. (Mátíù 6:9, 10) Ó máa wá hàn kedere pé Alákòóso tó dáa ni Jèhófà, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Jèhófà á wá pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run, títí kan gbogbo àwọn èèyàn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfihàn 20:7-10) Tí Ìjọba Ọlọ́run bá ti tún ayé yìí ṣe, kò tún ní sí ìṣòro kankan mọ́ títí láé!

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ohun tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

      4. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ìjọba èèyàn

      “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí ìyà tí ìjọba èèyàn fi ń jẹ aráyé.

      Ka Dáníẹ́lì 2:44 àti 2 Tẹsalóníkà 1:6-8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ máa ṣe sí ìjọba èèyàn àtàwọn tó ń ti ìjọba èèyàn lẹ́yìn?

      • Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù ṣe mú kó dá ẹ lójú pé wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ fún gbogbo èèyàn?

      Jésù ti di Ọba ní ọ̀run, ó ń ṣàkóso ayé tó ti di Párádísè.

      5. Jésù ni Ọba tó yẹ wá

      Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣe aráyé láǹfààní. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jésù ṣe fi hàn pé ó ń wu òun gan-an láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́ àti pé ó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.

      FÍDÍÒ: Jésù Jẹ́ Ká Mọ Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe (1:13)

      Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. Èwo lára àwọn ohun rere tó wà nísàlẹ̀ yìí ló ń wù ẹ́ jù? Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun rere náà.

      NÍGBÀ TÍ JÉSÙ WÀ LÁYÉ, Ó . . .

      LÁTỌ̀RUN, JÉSÙ MÁA . . .

      • mú kí ìjì líle pa rọ́rọ́.​—Máàkù 4:36-41.

      • mú kí ayé di ibi tó rẹwà, tó sì tura láti gbé​—Àìsáyà 35:1, 2.

      • fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní oúnjẹ.​—Mátíù 14:17-21.

      • mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ wà láyé, ó sì máa kárí gbogbo èèyàn.​—Sáàmù 72:16.

      • mú ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn lára dá.​—Lúùkù 18:35-43.

      • mú kí ara gbogbo èèyàn jí pépé.​—Àìsáyà 33:24.

      • jí àwọn òkú dìde.​—Lúùkù 8:49-55.

      • jí àwọn òkú dìde, àwọn èèyàn ò sì ní máa kú mọ́.​—Ìfihàn 21:3, 4.

      6. Ìjọba Ọlọ́run máa mú káyé tura gan-an

      Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún àwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jèhófà ṣe máa lo Ọmọ rẹ̀, Jésù, láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn.

      FÍDÍÒ: Àwọn Ohun Àgbàyanu Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la (4:38)

      Ka Sáàmù 145:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́”?

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Táwa èèyàn bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, a lè yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé fúnra wa.”

      • Àwọn ìṣòro wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú, àmọ́ tó jẹ́ pé ìjọba èèyàn ò lè yanjú wọn láé?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún àwa èèyàn. Ó máa sọ gbogbo ayé di Párádísè, àwọn èèyàn rere nìkan ló máa wà ní gbogbo ayé, wọ́n á sì máa jọ́sìn Jèhófà títí láé.

      Kí lo rí kọ́?

      • Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?

      • Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

      • Èwo lára àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ló ń wù ẹ́ jù?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́.

      “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá.”—Mátíù 24:21.

      “Kí Ni Ìpọ́njú Ńlá?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn ìdílé ṣe lè máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe.

      Wo Ara Rẹ Bíi Pé O Wà ní Párádísè (1:50)

      Ka ìtàn tí àkòrí ẹ̀ sọ pé, “Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ń Jà Gùdù Lọ́kàn Mi,” kó o lè rí bí ọkùnrin kan tó máa ń bá ìjọba fa wàhálà ṣe rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ń wá.

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2012)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́