-
Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ AláàánúTẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
8 Ọba pàápàá ronú pìwà dà nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jónà. Nítorí pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ ìgúnwà olówó iyebíye, ó sì wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ bíi tàwọn aráàlú, kódà ó “jókòó nínú eérú.” Lẹ́yìn tí ọba àti àwọn “ẹni ńlá” rẹ̀, ìyẹn àwọn ìjòyè rẹ̀, ti fikùn lukùn, ọba pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ará ìlú Nínéfè gbààwẹ̀. Bí ọba ṣe sọ ààwẹ̀ téèyàn lè gbà nígbà tó bá wù ú di ọ̀ranyàn fún gbogbo aráàlú nìyẹn o! Ọba pàṣẹ pé kí gbogbo aráàlú wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, kí wọ́n sì tún wọ̀ ọ́ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.b Ó gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé òótọ́ làwọn èèyàn òun máa ń hùwà ibi àti ìwà ipá. Níwọ̀n bí ọba sì ti rò pé Ọlọ́run tòótọ́ máa ṣàánú àwọn tó bá rí bí àwọn ṣe ronú pìwà dà, ó ní: ‘Ọlọ́run lè yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò, kí a má bàa ṣègbé.’—Jónà 3:6-9.
-
-
Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ AláàánúTẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
b Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn Herodotus tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì sọ pé nígbà tí àwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ogun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà wọn.
-