ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Ọlọ́run mú kí Jónà ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, pé ó ń banú jẹ́ torí pé igi lásán làsàn kú, igi tó kàn hù jáde lọ́sàn-án kan òru kan, tí kì í ṣe póun ló gbìn ín, tí kò sì mọ nǹkan kan nípa bó ṣe dàgbà. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá sọ pé: “Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn, yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?”—Jónà 4:10, 11.d

      Ṣó o rí bí ẹ̀kọ́ tí Jèhófà kọ́ Jónà ti ṣe pàtàkì tó? Jónà ò mọ nǹkan kan nípa bí igi yẹn ṣe dàgbà. Àmọ́ Jèhófà ló dá àwọn ará Nínéfè, òun ló sì ń pèsè fún wọn bó ti ń ṣe fún gbogbo nǹkan alààyè tó wà láyé. Kí tiẹ̀ nìdí tí ikú igi kan ṣoṣo péré fi ní láti ká Jónà lára ju ikú àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà [120,000] lọ, tó fi mọ́ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn? Ṣé kì í ṣe torí pé Jónà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ro tara ẹ̀ nìkan báyìí? Ó ṣe tán, àǹfààní tó rí lára igi yẹn ló jẹ́ kó dùn ún nígbà tí igi náà kú. Ó ní láti jẹ́ pé ìmọ́tara-ẹni-nìkan náà ló mú kí Jónà máa bínú nígbà tí Ọlọ́run ò pa ìlú Nínéfè run, torí pé ó fẹ́ kọ́rọ̀ òun ṣẹ, káwọn èèyàn wọ̀nyẹn má bàa mú òun lónírọ́.

      Ẹ̀kọ́ ńlá mà lèyí o! Ṣé Jónà fi ṣàríkọ́gbọ́n báyìí? Ìbéèrè tí Jèhófà bi Jónà yẹn ló gbẹ̀yìn ìwé Jónà nínú Bíbélì, ó sì ń dún gbọnmọgbọnmọ. Àwọn kan tó ń ṣe lámèyítọ́ lè máa sọ pé Jónà ò dáhùn ìbéèrè yẹn. Àmọ́ ìdáhùn Jónà wà níbẹ̀. Ìwé tí Jónà kọ yẹn ló fi dáhùn ìbéèrè yẹn. Ẹ̀rí fi hàn pé Jónà fúnra ẹ̀ ló fọwọ́ ara ẹ̀ kọ ìwé tó ń jẹ́ orúkọ ẹ̀ yẹn. Ìwọ náà fojúunú wo bí wòlíì yẹn ṣe ń fọwọ́ ara ẹ̀ kọ ìtàn yìí sílẹ lẹ́yìn tó pa dà sílùú ìbílẹ̀ rẹ̀ láyọ̀ àti lálàáfíà. A lè máa fojúunú wo Jónà nígbà tó ti darúgbó, tó ti wá gbọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní ti pọ̀ sí i, tó sì wá ń mi orí láti fi hàn pé ó ń kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn, bó ti ń kọ àwọn àṣìṣe tóun fúnra ẹ̀ ṣe sílẹ̀, bó ṣe ya olọ̀tẹ̀ àti bó ṣe fi agídí kọ̀ jálẹ̀ láti ṣàáánú àwọn ẹlòmíì. Ẹ̀rí fi hàn pé Jónà kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n tí Jèhófà fún un. Ó kọ́ béèyàn ṣe lè jẹ́ aláàánú. Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • d Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ọwọ́ ọ̀tún àti òsì fi hàn pé wọn ò dákan mọ̀ tọ́rọ̀ bá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́