ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!
    Ilé Ìṣọ́—2003 | August 15
    • 15. Lọ́rọ̀ ara rẹ, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 4:1-4?

      15 Bá a bá tún padà lọ wo ìwé Míkà, a óò rí i pé ìrètí tí ń múni lọ́kàn yọ̀ ló kéde tẹ̀ lé e. Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni lọ́kàn le ló wà nínú Míkà 4:1-4! Ara ọ̀rọ̀ tí Míkà sọ níbẹ̀ ni pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. . . . Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá tí ó jìnnà réré. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”

  • A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!
    Ilé Ìṣọ́—2003 | August 15
    • 17 Níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Míkà, ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ni gbogbo èèyàn yóò máa ṣe kárí ayé láìpẹ́. Lóde òní, àwọn èèyàn “tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ni à ń kọ́ ní ọ̀nà Jèhófà. (Ìṣe 13:48) Jèhófà ń ṣe ìdájọ́, ó sì ń mú àwọn ọ̀ràn tọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n fara mọ́ Ìjọba náà. Wọn yóò la “ìpọ́njú ńlá” já gẹ́gẹ́ bí ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà. (Ìṣípayá 7:9, 14) Níwọ̀n bí wọ́n ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, lónìí pàápàá wọ́n ń gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹlẹgbẹ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìdùnnú ńlá gbáà ló jẹ́ láti wà lára wọn!

      A Ti Pinnu Láti Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà

      18. Kí ni ‘jíjókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ ẹni’ ń ṣàpẹẹrẹ?

      18 Lọ́jọ́ tiwa, tí ìbẹ̀rù bo ayé mọ́lẹ̀ bámúbámú yìí, inú wa dùn gidigidi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà Jèhófà. À ń fi ìháragàgà retí àkókò tó ti sún mọ́lé yìí, tí gbogbo èèyàn tó fẹ́ràn Ọlọ́run yóò ṣíwọ́ kíkọ́ṣẹ́ ogun jíjà, tí wọ́n á tún jókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn. Inú ọgbà àjàrà la sábà máa ń gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sí. (Lúùkù 13:6) Jíjókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ ẹni dúró fún wíwà ní àlàáfíà, ipò aásìkí àti ààbò. Àní nísinsìnyí pàápàá, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ń fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ààbò tẹ̀mí. Nígbà tí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá dé lábẹ́ Ìjọba náà, àyà wa ò ní já mọ́ rárá, ọkàn wa á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́