ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa
    Ilé Ìṣọ́—2000 | February 1
    • 14-16. Ní ìbámu pẹ̀lú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Jèhófà àti àwọn ọ̀tá wọn?

      14 Ní Amágẹ́dónì, ìdàrúdàpọ̀ yóò bá àwọn tó ń gbìyànjú láti pa “àwọn ẹni àmì òróró” Jèhófà run. Ní ìbámu pẹ̀lú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrìnlá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún, wòlíì náà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó ní: “O fi àwọn ọ̀pá tirẹ̀ gún orí àwọn jagunjagun rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbéra bí ìjì líle láti tú mi ká. Ayọ̀ pọ̀rọ́ wọn dà bí ti àwọn tí ó ti pinnu tán láti jẹ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ run ní ibi ìlùmọ́. O fi àwọn ẹṣin rẹ rin òkun já, la òkìtì alagbalúgbú omi.”

  • Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa
    Ilé Ìṣọ́—2000 | February 1
    • 16 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò pin síbẹ̀ yẹn o. Jèhófà yóò lo agbo ọmọ ogun tẹ̀mí tí agbára wọn ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ láti yanjú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó ṣẹ́kù. Ní lílo “àwọn ẹṣin,” ìyẹn ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ́run tó wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, Jèhófà yóò yan gẹ́gẹ́ bí akọgun gba inú “òkun” àti “òkìtì alagbalúgbú omi” kọjá, ìyẹn ni, ìran ènìyàn tó jẹ́ ọ̀tá, tí wọ́n ń ru gùdù. (Ìṣípayá 19:11-21) Nígbà náà la óò mú àwọn ẹni ibi kúrò ní ilẹ̀ ayé. Ẹ ò rí i pé ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá yìí fakíki!

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́