ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ẹ Dúró Dè Mí”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | March 1
    • 13. Ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ wo ni Sefaniah kéde lòdì sí Moabu, Ammoni, àti Assiria?

      13 Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Sefaniah, Jehofa tún fi ìbínú rẹ̀ hàn sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fìyà jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó polongo pé: “Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu, àti ẹlẹ́yà àwọn ọmọ Ammoni, nípa èyí tí wọn ti kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn. Nítorí náà bí èmi ti wà, ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí, Ọlọrun Israeli, Dájúdájú Moabu yóò dà bíi Sodomu, àti àwọn ọmọ Ammoni bíi Gomorra, bíi títàn wèrèpè, àti bí ihò iyọ̀, àti ìdahoro títí láé . . . Òun óò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí ìhà àríwá, yóò sì pa Assiria run; yóò sì sọ Ninefe di ahoro, àti di gbígbẹ bí aginjù.”—Sefaniah 2:8, 9, 13.

      14. Ẹ̀rí wo ní ó wà pé, àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì “gbé ara wọn ga” sí àwọn ọmọ Israeli àti Ọlọrun wọn, Jehofa?

      14 Moabu àti Ammoni ti jẹ́ ọ̀tá Israeli tipẹ́tipẹ́. (Fi wé Onidajọ 3:12-14.) Òkúta Moabu, tí ó wà ní Ilé Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé ti Louvre ní Paris, ní àkọlé kan tí ó ní ọ̀rọ̀ ìfọ́nnu tí Ọba Meṣa ará Moabu sọ nínú. Ó fi ìgbéraga sọ bí òún ṣe ṣẹ́gun àwọn ìlú ńlá Israeli mélòó kan pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọlọrun rẹ̀ Kemoṣi. (2 Awọn Ọba 1:1) Jeremiah, alájọgbáyé Sefaniah, sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ará Ammoni ṣe gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Israeli ti Gadi ní orúkọ Malkomu ọlọrun wọn. (Jeremiah 49:1) Ní ti Assiria, Ọba Ṣalamaneseri Karùn-ún ti dó ti Samaria, ó sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ ní nǹkan bí ọ̀rúndún kan ṣáájú ọjọ́ Sefaniah. (2 Awọn Ọba 17:1-6) Kó pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, Ọba Sennakaribi kọlu Juda, ó ṣẹ́gun púpọ̀ nínú àwọn ìlú ńlá olódi rẹ̀, àní ó tilẹ̀ halẹ̀ mọ́ Jerusalemu. (Isaiah 36:1, 2) Ní tòótọ́, agbẹnusọ fún ọba Assiria gbéra ga sí Jehofa nígbà tí ó ń fi dandan gbọ̀n béèrè pé kí Jerusalemu túúbá.—Isaiah 36:4-20.

  • “Ẹ Dúró Dè Mí”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | March 1
    • 15. Báwo ni Jehofa yóò ṣe tẹ́ àwọn ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbéra ga sí àwọn ènìyàn rẹ̀ lógo?

      15 Orin Dafidi 83 mẹ́nu kan àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan, tí ó ní Moabu, Ammoni, àti Assiria nínú, tí ó gbéraga sí Israeli, tí ó sì fi tìhàlẹ̀tìhàlẹ̀ sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ké wọn kúrò láti máa wà ní orílẹ̀-èdè; kí orúkọ Israeli kí ó má ṣe sí ní ìrántí mọ́.” (Orin Dafidi 83:4) Wòlíì náà Sefaniah fi tìgboyàtìgboyà kéde pé, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́kàn gíga wọ̀nyí àti àwọn ọlọrun wọn ni Jehofa àwọn ọmọ ogun yóò tẹ́ lógo. “Èyí ni wọn óò ní nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ti kẹ́gàn, wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí ènìyàn Oluwa àwọn ọmọ ogun. Oluwa yoo jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn: nítorí òun óò mú kí gbogbo òrìṣà ilẹ̀ ayé kí ó rù; ènìyàn yóò sì máà sìn ín, olúkúlùkù láti ipò rẹ̀ wá, àní gbogbo erékùṣù àwọn kèfèrí.”—Sefaniah 2:10, 11.

  • “Ẹ Dúró Dè Mí”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | March 1
    • 17. Nígbà wo àti báwo ni ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ ti Sefaniah jẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè?

      17 Kò bá àwọn tí wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ yẹn lójijì. Ọ̀pọ̀ fojú rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah. Ní ọdún 632 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a ṣẹ́gun Ninefe, a sì pa á run nípasẹ̀ ìfohùnṣọ̀kan àwọn ará Babiloni, Media, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí wọ́n wá láti ìhà àríwá, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ àwọn Skitiani. Òpìtàn, Will Durant sọ pé: “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Babiloni lábẹ́ Nabopolassar dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Media lábẹ́ Cyaxares àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Skitiani láti Caucasus, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ibi ìsádi ìhà àríwá pẹ̀lú ìrọ̀rùn yíyani lẹ́nu àti ìyára kánkán. . . . Lójijì Assiria di àwátì nínú ìtàn.” Ohun tí Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gan-an nìyí.—Sefaniah 2:13-15.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́