-
Dúró Sí Ibi Ààbò JèhófàIlé Ìṣọ́—2013 | February 15
-
-
8. (a) Nígbà míì, kí ni àwọn òkè máa ń dúró fún nínú Bíbélì? (b) Kí ni “òkè ńlá igi ólífì” dúró fún?
8 A ti rí i nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà pé “ìlú” náà, tàbí Jerúsálẹ́mù dúró fún Ìjọba Ọlọ́run. Kí wá ni “òkè ńlá igi ólífì, èyí tí ó wà ní iwájú Jerúsálẹ́mù,” dúró fún? Báwo ni òkè náà ṣe máa “là ní àárín” tí yóò sì wá di òkè méjì? Kí sì nìdí tí Jèhófà fi pè é ní “àwọn òkè ńlá mi”? (Ka Sekaráyà 14:3-5.) Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo òkè láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba tàbí ìṣàkóso. Bákan náà, Bíbélì sábà máa ń sọ pé ìbùkún tàbí ààbò wá láti orí òkè Ọlọ́run. (Sm. 72:3; Aísá. 25:6, 7) Látàrí èyí, òkè ńlá igi ólífì náà dúró fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ìyẹn ìṣàkóso Jèhófà lórí àwọn ẹ̀dá rẹ̀.
-
-
Dúró Sí Ibi Ààbò JèhófàIlé Ìṣọ́—2013 | February 15
-
-
ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN BẸ̀RẸ̀ SÍ Í SÁ LỌ SÍ ÀFONÍFOJÌ NÁÀ!
11, 12. (a) Ìgbà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àfonífojì náà? (b) Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀?
11 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Ìkórìíra yẹn ti ń pọ̀ sí i láti ọdún 1914 tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé nínú rẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ọ̀tá ṣe inúnibíni rírorò sí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Wọ́n fi àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n, wọn ò lè pa ìsìn tòótọ́ run. Ní ọdún 1919, wọ́n dá wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run di òmìnira lọ́wọ́ ìsìn èké, ìyẹn Bábílónì Ńlá. (Ìṣí. 11:11, 12)a Ìgbà yẹn ni àwọn èèyàn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àfonífojì náà.
12 Láti ọdún 1919 ni Jèhófà ti ń bá a nìṣó láti máa dáàbò bo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín níbikíbi tí wọ́n bá wà lágbàáyé. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn sì ni ọ̀pọ̀ ìjọba ti ń gbìyànjú láti pa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́, wọ́n sì ti fi òfin de àwọn ìwé wa. Èyí ṣì ń bá a nìṣó láwọn orílẹ̀-èdè kan. Àmọ́, Jèhófà ò fàyè gba àwọn ìjọba yìí láti pa ìsìn tòótọ́ run. Ohun yòówù kí àwọn ìjọba ṣe, Jèhófà á ṣì máa fi agbára ńlá rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.—Diu. 11:2.
13. Báwo la ṣe lè dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá? Kí nìdí tó fi túbọ̀ ṣe pàtàkì báyìí pé ká dúró síbẹ̀?
13 Ọ̀nà tá a lè gbà dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá ni pé ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Òun àti Ọmọ rẹ̀ kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun mú wa kúrò níbi ààbò náà. (Jòh. 10:28, 29) Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà ká lè jẹ́ adúróṣinṣin lábẹ́ ìṣàkóso òun àti Ọmọ rẹ̀. A máa túbọ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. Torí náà, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé ká dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá.
-