-
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
19 Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Kí ni ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò? Kristẹni olóòótọ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà sọ pé: “Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni kẹ́nì kan mọ ìrora ẹlòmíì nínú ọkàn rẹ̀.” Ṣé ìrora wa tiẹ̀ kan Jèhófà? Wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà, ó ní: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.” (Àìsáyà 63:9) Kì í ṣe pé Jèhófà kàn rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, ó mọ̀ ọ́n lára. Ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ bó ṣe mọ̀ ọ́n lára tó, ó sọ pé: “Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.”b (Sekaráyà 2:8) Ká sòótọ́, tẹ́nì kan bá fọwọ́ kan ojú wa ó máa dùn wá gan-an. Èyí fi hàn pé tá a bá wà nínú ìṣòro, àánú wa máa ń ṣe Jèhófà gan-an. Kódà, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.
-
-
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
b Báwọn kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lẹni tó bá fọwọ́ kan àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tọwọ́ bọ ara ẹ̀ lójú tàbí pé ó ń tọwọ́ bọ Ísírẹ́lì lójú, kì í ṣe pé ó ń tọwọ́ bọ Ọlọ́run lójú. Àwọn adàwékọ kan ló túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yẹn torí wọ́n ka ọ̀rọ̀ yẹn sí àrífín. Bí wọ́n ṣe yí ẹsẹ Bíbélì yẹn pa dà kò jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò gan-an débi pé táwọn èèyàn ẹ̀ bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.
-