-
Ibukun Jehofa Níí MúniílàIlé-Ìṣọ́nà—1992 | December 1
-
-
A Ṣedajọ Wọn Lati Ọwọ ‘Oluwa Tootọ Naa’
18. (a) Dídé ta ni Jehofa kilọ nipa rẹ̀? (b) Nigba wo ni dídé si tẹmpili naa ṣẹlẹ, ta ni o ni ninu, ki sì ni iyọrisi rẹ̀ fun Israeli?
18 Jehofa nipasẹ Malaki tun kilọ pe oun yoo wá lati ṣedajọ awọn eniyan rẹ̀. “Kiyesi i, Emi o ran onṣẹ mi, yoo si tun ọ̀nà ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹyin ń wá, yoo de ni ojiji si tẹmpili rẹ̀, àní onṣẹ majẹmu naa, ti inu yin dùn si; kiyesi i, o ń bọ wá, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.” (Malaki 3:1) Nigba wo ni dide ti a ṣeleri sinu tẹmpili naa wáyé? Ni Matteu 11:10, Jesu fa asọtẹlẹ Malaki nipa onṣẹ ti yoo tun ọ̀nà ṣe yọ o si fihàn bi o ti nii ṣe pẹlu Johannu Arinibọmi. (Malaki 4:5; Matteu 11:14) Nitori naa ni 29 C.E., akoko naa fun idajọ ti de! Ta ni onṣẹ keji naa, onṣẹ majẹmu naa ti yoo bá Jehofa ‘Oluwa tootọ naa’ rìn wá sinu tẹmpili? Jesu funraarẹ ni, ati ni akoko iṣẹlẹ meji ó wá sinu tẹmpili ni Jerusalemu ati lọna amunijigiri o wẹ̀ ẹ́ mọ́, ni lílé awọn alabosi onipaṣipaarọ owó sita. (Marku 11:15-17; Johannu 2:14-17) Nipa akoko idajọ ti ọrundun kìn-ín-ní yii, Jehofa beere lọna alasọtẹlẹ pe: “Ta ni ó lè gba ọjọ wiwa rẹ̀? ta ni yoo si duro nigba ti o bá fi ara hàn?” (Malaki 3:2) Niti tootọ, Israeli kò duro. A bẹ wọn wò, wọn kò si kúnjú iwọn, ati ni 33 C.E., a ta wọn nù bii orilẹ-ede ayanfẹ Jehofa.—Matteu 23:37-39.
19. Ni ọ̀nà wo ni aṣẹku kan fi pada sọdọ Jehofa ni ọrundun kìn-ín-ní, ibukun wo ni wọn sì rí gbà?
19 Bi o ti wu ki o ri, Malaki pẹlu tun kọwe pe: “[Jehofa] gbọdọ jokoo gẹgẹ bi olùyọ́mọ́ ati olùwẹ̀mọ́ fadaka kan oun sì gbọdọ yọ́ awọn ọmọ Lefi mọ́; oun sì gbọdọ mu wọn ṣe kedere bii wura ati bii fadaka, dajudaju wọn yoo si jẹ awọn eniyan ti ń mu ọrẹ-ẹbọ ẹbun kan wa ninu ododo si Jehofa.” (Malaki 3:3, NW) Ni ibaramu pẹlu eyi, nigba ti a ta pupọ awọn wọnni ti wọn ń jẹwọ pe awọn ń ṣiṣẹsin Jehofa ni ọrundun kìn-ín-ní nù, awọn kan ni a wẹ̀mọ́ ti wọn wa sọdọ Jehofa, ti wọn ń ru awọn ẹbọ ti o ṣe itẹwọgba. Awọn wo? Awọn ti wọn ti dahunpada si Jesu, onṣẹ majẹmu naa ni. Ni Pentekosti 33 C.E., 120 ninu awọn ti wọn dahunpada wọnyi korajọpọ ni iyara oke kan ni Jerusalemu. Bi ẹmi mimọ ti fun wọn lokun, wọn bẹrẹsii pese ọrẹ-ẹbọ ẹbun ninu ododo, ati ni kiamọsa iye wọn ròkè. Laipẹ, wọn tankalẹ jakejado gbogbo Ilẹ-ọba Romu. (Iṣe 2:41; 4:4; 5:14) Nipa bayii, aṣẹku kan yipada sọdọ Jehofa.—Malaki 3:7.
20. Nigba ti a pa Jerusalemu ati tẹmpili run, ki ni o ṣẹlẹ si Israeli titun ti Ọlọrun?
20 Aṣẹku Israeli yii, ti o wá lati ni awọn Keferi ti a mú wọle ninu, gẹgẹ bi a ti le sọ ọ́, sinu gbòǹgbò-ìdí Israeli, jẹ “Israeli Ọlọrun” titun kan, orilẹ-ede kan tí awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti a fi ẹmi bi parapọ jẹ́. (Galatia 6:16; Romu 11:17) Ni 70 C.E., “ọjọ . . . ti . . . [ń] jo bi ina ileru” kan de sori Israeli nipa ti ara nigba ti a pa Jerusalemu ati tẹmpili rẹ̀ run lati ọwọ́ awọn ọmọ ogun Romu. (Malaki 4:1; Luku 19:41-44) Ki ni o ṣẹlẹ si Israeli tẹmi ti Ọlọrun naa? Jehofa fi ‘ìyọ́nú hàn fun wọn, gẹgẹ bi ọkunrin kan ti ń fi ìyọ́nú hàn fun ọmọkunrin rẹ̀ ti o ń ṣiṣẹsin in.’ (Malaki 3:17) Ijọ Kristian ẹni-ami-ororo naa fiyesi ikilọ alasọtẹlẹ Jesu. (Matteu 24:15, 16) Wọn laaja, ibukun Jehofa si ń baa lọ lati mu wọn lọ́rọ̀ nipa tẹmi.
21. Awọn ibeere wo ni o ṣẹku nipa Malaki 3:1 ati 10?
21 Ẹ wo idalare fun Jehofa ti eyi jẹ! Bi o ti wu ki o ri, bawo ni Malaki 3:1 ṣe ń ni imuṣẹ lonii? Bawo ni o ṣe yẹ ki Kristian kan dahunpada si iṣiri tí Malaki 3:10 pese lati mu gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura? Eyi ni a o jiroro ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti o tẹle e.
-
-
“Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | December 1
-
-
1. (a) Ni ọrundun karun-un B.C.E., ikesini wo ni Jehofa fun awọn eniyan rẹ̀? (b) Ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., ki ni o jẹ iyọrisi wíwá ti Jehofa wa sinu tẹmpili fun idajọ?
NI ỌRUNDUN karun-un B.C.E., awọn ọmọ Israeli ti di alaiṣootọ si Jehofa. Wọn ti fawọ idamẹwaa sẹhin wọn sì ti mu awọn ẹran alaiyẹ wá si tẹmpili bi irubọ. Bi eyi tilẹ ri bẹẹ, Jehofa ṣeleri pe bi wọn yoo bá mú gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura, oun yoo rọjo ibukun tobẹẹ ti ààyè kì yoo fi gbà á. (Malaki 3:8-10) Ni nǹkan bii 500 ọdun lẹhin naa, Jehofa, ti Jesu ṣoju fun gẹgẹ bii onṣẹ majẹmu Rẹ̀, wá sinu tẹmpili ni Jerusalemu fun idajọ. (Malaki 3:1) Israeli gẹgẹ bi orilẹ-ede ni a ri bi alaikunju oṣuwọn, ṣugbọn awọn ẹnikọọkan ti wọn pada sọdọ Jehofa ni a bukun ni jingbinni. (Malaki 3:7) A fi ororo yàn wọn lati di awọn ọmọkunrin Jehofa nipa ti ẹmi, iṣẹda titun kan, “Israeli Ọlọrun.”—Galatia 6:16; Romu 3:25, 26.
2. Nigba wo ni Malaki 3:1-10 yoo ni imuṣẹ ẹlẹẹkeji, ki sì ni a késí wa lati ṣe ni isopọ pẹlu eyi?
2 Ni nǹkan bii 1,900 ọdun lẹhin eyi, ni 1914, Jesu ni a gbé gorí ìtẹ́ bi Ọba Ijọba ọrun ti Ọlọrun, tí akoko sì tó fun awọn ọ̀rọ̀ onimiisi atọrunwa naa ni Malaki 3:1-10 lati ni imuṣẹ ẹlẹẹkeji. Ni isopọ pẹlu iṣẹlẹ ti ń ru imọlara soke yii, awọn Kristian lonii ni a késí lati mú gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura. Bi a ba ṣe bẹẹ, awa pẹlu yoo gbadun awọn ibukun tobẹẹ ti ààyè kì yoo fi gbà á.
3. Ta ni onṣẹ naa ti ń tun ọ̀nà ṣe niwaju Jehofa (a) ni ọrundun kìn-ín-ní? (b) ṣaaju ogun agbaye kìn-ín-ní?
3 Niti wíwá rẹ̀ sinu tẹmpili naa, Jehofa sọ pe: “Kiyesi i, Emi ó rán onṣẹ mi, yoo si tun ọ̀nà ṣe niwaju mi.” (Malaki 3:1) Gẹgẹ bi imuṣẹ ọrundun kìn-ín-ní fun eyi, Johannu Arinibọmi wá si Israeli ó sì ń waasu ironupiwada awọn ẹ̀ṣẹ̀. (Marku 1:2, 3) Iṣẹ́ imurasilẹ kankan ha wà ni isopọ pẹlu wíwá Jehofa sinu tẹmpili rẹ̀ lẹẹkeji bi? Bẹẹni. Ni awọn ẹwadun ṣaaju ogun agbaye kìn-ín-ní, awọn Akẹkọọ Bibeli farahan lori ibi-iran ayé ní kíkọ́ni ni ẹkọ Bibeli mimọ gaara ti wọn sì ń tudii awọn irọ alaibọla fun Ọlọrun, iru bii Mẹtalọkan ati ẹkọ iná ọ̀run-àpáàdì. Wọn tún ṣekilọ nipa opin Akoko awọn Keferi tí ń bọwa ni 1914. Ọpọlọpọ dahunpada si awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ otitọ wọnyi.—Orin Dafidi 43:3; Matteu 5:14, 16.
4. Ibeere wo ni a nilati yanju lakooko ọjọ Oluwa?
4 Ọdun 1914 bẹrẹ ohun ti Bibeli pe ni “ọjọ Oluwa.” (Ìfihàn 1:10) Awọn iṣẹlẹ ṣiṣe pataki gidigidi ni yoo wáyé lakooko ọjọ yẹn, o ni ninu dídá “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọ-inu naa” mọ yatọ ati yíyan iyẹn lati “ṣe olori gbogbo ohun ti [Ọ̀gá naa] ní.” (Matteu 24:45-47) Nigba naa lọ́hùn-ún ni 1914, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ṣọọṣi jẹwọ pe awọn jẹ Kristian. Awujọ wo ni Ọga naa, Jesu Kristi, yoo gba gẹgẹ bi ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa? Ibeere yẹn ni a reti pe ki o yanju nigba ti Jehofa wa sinu tẹmpili naa.
Wíwá Sinu Tẹmpili Tẹmi Naa
5, 6. (a) Si tẹmpili wo ni Jehofa wa fun idajọ? (b) Iru idajọ wo ni Kristẹndọm gbà lati ọ̀dọ̀ Jehofa?
5 Bi o ti wu ki o ri, sinu tẹmpili wo ni ó wá? Ni kedere kìí ṣe sinu tẹmpili gidi kan ni Jerusalemu. Eyi ti o kẹhin lara awọn tẹmpili wọnyẹn ni a parun nigba naa lọ́hùn-ún ni 70 C.E. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa ní tẹmpili titobi ju kan tí eyi ti o wà ni Jerusalemu jẹ ojiji iṣaaju fun. Paulu sọrọ nipa tẹmpili titobi ju yii o si fihàn bi itobilọla rẹ̀ ti ri nitootọ, pẹlu ibi mimọ kan ni ọrun ati agbala kan nihin-in lori ilẹ̀-ayé. (Heberu 9:11, 12, 24; 10:19, 20) Sinu tẹmpili tẹmi titobi yii ni Jehofa wá fun iṣẹ́ idajọ kan.—Fiwe Ìfihàn 11:1; 15:8.
6 Nigba wo ni iyẹn ṣẹlẹ? Ni ibamu pẹlu ẹ̀rí rẹpẹtẹ ti o wà larọọwọto, ni 1918 ni.a Ki ni iyọrisi rẹ̀? Niti Kristẹndọm, Jehofa rí eto-ajọ kan ti ọwọ́ rẹ̀ kun fun ẹ̀jẹ̀, eto-igbekalẹ isin ẹlẹgbin kan ti o ti fi iwakiwa gbé araarẹ̀ tà fun ayé yii, ni siso araarẹ̀ pọ̀ pẹlu awọn alaasiki ti o si ń ni awọn otoṣi lara, ni kíkọ́ wọn ni awọn ẹkọ oloriṣa dipo ki o sọ ijọsin mimọgaara dàṣà. (Jakọbu 1:27; 4:4) Nipasẹ Malaki, Jehofa ti kilọ pe: “Emi o sì ṣe ẹlẹ́rìí yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura èké, ati awọn ti o ni alágbàṣe lara ninu ọ̀yà rẹ̀, ati opó, ati alainibaba.” (Malaki 3:5) Kristẹndọm ti ṣe gbogbo eyi ati eyi ti o buru ju. Nigba ti o fi maa di 1919 o ti wá hàn kedere pe Jehofa ti dá a lẹbi iparun papọ pẹlu iyoku Babiloni Nla, isin eke agbaye ràgàjì naa. Lati ìgbà naa lọ, ipe naa ti jade lọ sọdọ awọn ẹni ọlọkantitọ pe: “Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹyin eniyan mi.”—Ìfihàn 18:1, 4.
-