ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!
    Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
    • Àwọ̀n Ńlá

      15, 16. (a) Sọ àpèjúwe àwọ̀n ńlá náà ní ṣókí. (b) Kí ni àwọ̀n ńlá náà ṣàpẹẹrẹ, apá wo lára ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù sì fi tọ́ka sí?

      15 Kì í ṣe bí àwọn tó pe ara wọn ní ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ṣe pọ̀ wọ̀ǹtì-wọnti tó ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kí wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn. Kókó pàtàkì yìí ni Jésù fi àpèjúwe míì tó ṣe nípa ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn àpèjúwe àwọ̀n ńlá, tọ́ka sí. Ó ní: “Ìjọba ọ̀run tún dà bí àwọ̀n ńlá kan, tí a jù sínú òkun, tí ó sì kó ẹja onírúurú jọ.”—Mát. 13:47.

      16 Onírúurú ẹja ni àwọ̀n ńlá, tó ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kó. Jésù wá sọ pé: “Nígbà tí [àwọ̀n náà] kún, wọ́n fà á gòkè sí etíkun àti pé, ní jíjókòó, wọ́n kó àwọn èyí àtàtà sínú àwọn ohun èlò, ṣùgbọ́n àwọn tí kò yẹ ni wọ́n dànù. Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan: àwọn áńgẹ́lì yóò jáde lọ, wọn yóò sì ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo, wọn yóò sì jù wọ́n sínú ìléru oníná. Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.”—Mát. 13:48-50.

      17. Ìgbà wo ni iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ tí àpèjúwe àwọ̀n ńlá yẹn tọ́ka sí máa wáyé?

      17 Ǹjẹ́ ìdájọ́ ìkẹyìn fáwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́, èyí tí Jésù sọ pé ó máa wáyé nígbà tí òun bá dé nínú ògo ńlá, ni ìyàsọ́tọ̀ inú àpèjúwe yìí ń tọ́ka sí? (Mát. 25:31-33) Rárá o. Ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù lákòókò ìpọ́njú ńlá ni ìdájọ́ ìkẹyìn yẹn yóò wáyé. Àmọ́, bí àpèjúwe yẹn ṣe sọ, yíya àwọn ẹja àtàtà àti èyí tí kò yẹ sọ́tọ̀ wáyé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”b Àkókò tá a wà yìí gan-an sì ni, ìyẹn àkókò tó kángun sí ìpọ́njú ńlá náà. Báwo ni iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ yẹn ṣe ń wáyé lákòókò yìí?

      18, 19. (a) Báwo la ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ náà lákòókò yìí? (b) Kí ló yẹ káwọn olóòótọ́ ọkàn ṣe? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lójú ewé 21.)

      18 Lákòókò wa yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tí ẹja inú àpèjúwe yẹn dúró fún là ń pè jáde látinú òkun ọmọ aráyé tó lọ salalu, pé kí wọ́n wá sínú ìjọ Jèhófà. Àwọn kan máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, àwọn míì máa ń wá sáwọn ìpàdé wa, àwọn míì sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣé gbogbo wọn ló máa ń di ojúlówó Kristẹni? Rárá o. Lóòótọ́, a lè ti ‘fà wọ́n gòkè sí etíkun,’ ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wa pé “èyí àtàtà” ni a kó sínú àwọn ohun èlò, èyí tó dúró fún ìjọ Kristẹni. Àwọn tí kò yẹ ni wọ́n kó dà nù, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọn yóò dà wọ́n sínú ìléru oníná, èyí tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ọjọ́ iwájú.

      19 Bí àwọn ẹja kan ṣe jẹ́ èyí tí kò yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ti dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró. Àwọn míì tí àwọn òbí wọn jẹ́ Kristẹni kò fẹ́ di ọmọlẹ́yìn tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù. Wọn ò ṣe tán láti di olùjọsìn Jèhófà, àwọn míì sì sin Jèhófà fúngbà díẹ̀ wọ́n jáwọ́.c (Ìsík. 33:32, 33) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn olóòótọ́ ọkàn jẹ́ kí Ọlọ́run kó wọn jọ sínú ìjọ rẹ̀ kó tó di ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀, kí wọ́n má sì kúrò níbi ààbò náà.

  • Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!
    Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
    • 20, 21. (a) Kí la rí kọ́ látinú àyẹ̀wò àwọn àpèjúwe Jésù nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? (b) Kí ni ìpinnu rẹ báyìí?

      20 Kí la ti wá rí kọ́ látinú àyẹ̀wò ráńpẹ́ tá a ṣe nípa àwọn àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? Àkọ́kọ́, bí irúgbìn hóró músítádì tí Jésù sọ ṣe dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ń kọbi ara sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró kó má tàn kálẹ̀! (Aísá. 54:17) Láfikún sí i, Ọlọ́run tún ń dáàbò bo àwọn tó ń wá “ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji [igi] náà” kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ayé burúkú rẹ̀. Ìkejì, Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. Gẹ́lẹ́ bí ìwúkàrà tí obìnrin yẹn fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ṣe sọ gbogbo rẹ̀ di wíwù láìjẹ́ pé obìnrin yẹn fojú rí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé, a kì í sábà fojú rí ìtẹ̀síwájú tó ń wáyé, àmọ́ ó ń ṣẹlẹ̀ dájúdájú! Ìkẹta, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ìhìn rere ló ń di ọmọlẹ́yìn. Àwọn kan ti dà bí ẹja tí kò yẹ, tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀.

  • Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!
    Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
    • b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé apá mìíràn lára iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ni Mátíù 13:39-43 ń tọ́ka sí, àkókò kan náà ló ní ìmúṣẹ pẹ̀lú àpèjúwe àwọ̀n ńlá, ìyẹn nígbà “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ ẹja ìṣàpẹẹrẹ náà kò dáwọ́ dúró, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fífúnrúgbìn àti kíkórè kò ti dáwọ́ dúró ní gbogbo àkókò òpin yìí.—Ilé Ìṣọ́, October 15, 2000, ojú ìwé 25 àti 26; Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, ojú ìwé 178 sí 181, ìpínrọ̀ 8 sí 11.

      c Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ti dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ dúró tàbí tí kò wá sípàdé àwọn èèyàn Jèhófà mọ́ ti dẹni tí kò yẹ táwọn áńgẹ́lì máa ṣà dà nù nìyẹn? Rárá o! Tírú àwọn bẹ́ẹ̀ bá ṣe tán láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà tọkàntọkàn, Jèhófà yóò gbà wọ́n padà.—Mál. 3:7.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́