ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Ìdánwò
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Tí Jésù Tọ́ Ọ Sọ́nà

      11. Ibo ni Jésù mú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      11 Láìpẹ́ sí ìgbà tí ọwọ́ wọn dí gan-an yìí, Jésù mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn kan lọ ìrìn àjò jíjìn kan lápá àríwá. Apá àríwá yìí, ní ìkángun Ilẹ̀ Ìlérí, ni Òkè Hámónì wà. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń rí ṣóńṣó orí òkè yìí tí yìnyín bò láti orí Òkun Gálílì tó mọ́. Bí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ń sún mọ́ òkè yìí, lójú ọ̀nà olókè tó lọ sáwọn abúlé tó wà ní agbègbè Kesaréà ti Fílípì tí wọ́n gbà, ni wọ́n túbọ̀ ń rí bó ṣe ga tó.b Àgbègbè ilẹ̀ olókè tó fani mọ́ra yìí, tí wọ́n ti lè rí èyí tó pọ̀ jù nínú Ilẹ̀ Ìlérí níhà gúúsù, ni Jésù ti bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìbéèrè pàtàkì kan.

      12, 13. (a) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ mọ ẹni tí àwọn èèyàn ń rò pé òun jẹ́? (b) Báwo ni èsì tí Pétérù fún Jésù ṣe fi hàn pé ó ní ojúlówó ìgbàgbọ́?

      12 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” A lè fojú inú wo bí Pétérù á ṣe máa wojú Jésù, táá sì máa ronú nípa bí Ọ̀gá rẹ̀ yìí ṣe jẹ́ aláàánú àti onílàákàyè tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jésù fẹ́ mọ ẹni tí àwọn èèyàn ń rò pé òun jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. Ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá fèsì, wọ́n sì sọ onírúurú èrò tí kò tọ̀nà tí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn ní nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Àmọ́ Jésù fẹ́ mọ nǹkan míì sí i. Ó fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ọmọlẹ́yìn òun, tó sún mọ́ òun dáadáa, mọ ẹni tí òun jẹ́ gan-an. Torí náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?”—Lúùkù 9:18-20.

  • Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Ìdánwò
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • b Bí wọ́n ṣe gbéra ní etí Òkun Gálílì tó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọọlẹ̀ gan-an ní nǹkan bí igba-ó-lé-mẹ́wàá [210] mítà sí ìtẹ́jú òkun, wọ́n rìnrìn àjò kìlómítà méjìdínláàádọ́ta [48] lọ sí àgbègbè olókè tó ga tó àádọ́ta-dín-nírinwó [350] mítà sí ìtẹ́jú òkun. Ibi tó fani mọ́ra gan-an ni àgbègbè ilẹ̀ olókè tí wọ́n ń gbà lọ yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́