ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fifi Ẹmi Ifara-ẹni-rubọ Ṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | June 1
    • 2. Ki ni idahunpada Peteru si awọn ọ̀rọ̀ Jesu nipa ijiya Rẹ̀ ọjọ-iwaju, bawo sì ni Jesu ṣe dahunpada?

      2 Ó kù rébété fun Jesu lati kú. Peteru, bi o ti wu ki o ri, fi ìrunú hàn si ohun ti o farajọ èrò buruku bẹẹ nipa iku. Oun kò lè gbà pe Messia ni a o pa niti gidi. Nitori naa, Peteru gbójúgbóyà lati bá Ọ̀gá rẹ̀ wí. Bi awọn èrò-ọkàn didara julọ ti sún un, ó fi inúfùfù rọ̀ ọ́ pe: “Ki a má ri i, Oluwa, kì yoo rí bẹẹ fun ọ.” Ṣugbọn Jesu kọ inurere àṣìní Peteru yii loju-ẹsẹ, ni pàtó bi ẹnikan yoo ti tẹ ori ejo aṣekupani fọ́. “Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ ni iwọ jẹ́ fun mi: iwọ kò ro ohun tii ṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi tii ṣe ti eniyan.”—Matteu 16:22, 23.

      3. (a) Bawo ni Peteru ṣe fi aimọọmọ sọ araarẹ di aṣoju Satani? (b) Bawo ni Peteru ṣe jẹ́ okuta idigbolu si ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ?

      3 Peteru ti sọ araarẹ di aṣoju Satani laimọọmọ. Idahun Jesu lọna mimuna ti jẹ́ tipinnutipinnu gẹgẹ bi ìgbà ti ó dá Satani lohun ninu aginju. Nibẹ ni Eṣu ti gbiyanju lati dán Jesu wò pẹlu igbesi-aye pẹ̀lẹ́tùù, ipo-ọba laisi ijiya. (Matteu 4:1-10) Nisinsinyi Peteru ń fun un niṣiiri lati maṣe lekoko mọ́ araarẹ. Jesu mọ pe eyi kìí ṣe ifẹ-inu Baba oun. Igbesi-aye rẹ̀ gbọdọ jẹ́ ọ̀kan ti o jẹ́ ti ifara-ẹni-rubọ, kìí ṣe ti onítẹ̀ẹ́ra-ẹni-lọ́rùn. (Matteu 20:28) Peteru di okuta idigbolu si iru ipa-ọna kan bẹẹ; ìbánikẹ́dùn ọlọkanrere rẹ̀ wá di pańpẹ́.a Jesu, bi o ti wu ki o ri, ríran kedere pe bi oun bá fààyè gba èrò eyikeyii nipa igbesi-aye ti o bọ́ lọwọ ifirubọ, oun yoo kuna ojurere Ọlọrun nipa didi ẹni ti ọwọ́ ṣìnkún pańpẹ́ Satani mú.

      4. Eeṣe ti igbesi-aye itura onikẹẹra-ẹni bajẹ kìí fií ṣe ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀?

      4 Ironu Peteru, nitori naa, nilo itunṣebọsipo. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ si Jesu duro fun èrò eniyan, kìí ṣe ti Ọlọrun. Ti Jesu kọ ni igbesi-aye oníkẹ̀ẹ́ra-ẹni bajẹ, ọ̀nà rirọrun lati bọ́ kuro lọwọ ijiya; bẹẹ ni kò sì yẹ ki irú igbesi-aye bẹẹ wà fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀, nitori pe Jesu sọ tẹlee fun Peteru ati awọn ọmọ-ẹhin yooku pe: “Bi ẹnikan bá ń fẹ́ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o sì gbé [òpó-igi ìdálóró, NW] rẹ̀, ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin.”—Matteu 16:24.

  • Fifi Ẹmi Ifara-ẹni-rubọ Ṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | June 1
    • a Ni èdè Griki, “okuta ìdìgbòlù” (σκάνδαλον, skanʹda·lon) ni “orukọ apakan pańpẹ́ ti a ń so ìjẹ mọ, ni ipilẹṣẹ, fun idi yii, ó jẹ́ pańpẹ́ tabi ikẹkun funraarẹ.”—Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́