ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | July 15
    • “Pẹ̀lúpẹ̀lù bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un ti ìwọ tirẹ̀ méjì: bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ mú arákùnrin rẹ bọ̀sípò. Ṣùgbọ́n bí kò bá gbọ́ tìrẹ, nígbà náà ni kí ìwọ kí ó mú ẹnìkan tàbí méjì pẹ̀lú araarẹ, kí gbogbo ọ̀rọ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta baà le fi ìdí múlẹ̀. Bí ó bá sí kọ̀ láti gbọ́ wọn, wí fún ìjọ ènìyàn Ọlọrun: bí ó ba sì kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọrun, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ àti agbowóòde.”​—⁠Matteu 18:​15-⁠17.

  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | July 15
    • Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lè ṣaláìtó. Láti bójútó ipò ọ̀ràn yẹn, Jesu wí pé: “Mú ẹnìkan tàbí méjì pẹ̀lú araarẹ.” Ìwọ̀nyí lè jẹ́ àwọn tí ọ̀ràn náà kọ́kọ́ ṣojú wọn. Bóyá wọ́n ti gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn ẹni náà fi ọ̀rọ̀ èké ba ẹnìkejì jẹ́, tàbí bóyá àwọn wọnnì tí a mú lọ náà ti jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àdéhùn alákọsílẹ̀ kan èyí tí àwọn ènìyàn méjèèjì náà kò fohùnṣọ̀kan lé lórí nísinsìnyí. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn wọnnì tí a mú lọ lè di ẹlẹ́rìí nígbà tí a bá mú àwọn kókó abájọ èyíkéyìí bí àwọn gbólóhùn ẹ̀rí tí a fọwọ́sí tàbí tí a sọ lọ́rọ̀ ẹnu, jáde láti ṣàlàyé ìdí fún ìṣòro náà. Níhìn-⁠ín bákan náà, kìkì iye kíkéré jùlọ tí ó bá ṣeéṣe​—⁠“ẹnìkan tàbí méjì”⁠—​ni ó yẹ kí ó mọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Èyí kì yóò jẹ́ kí àwọn nǹkan burú síi bí ó bá jẹ́ pé èdèkòyedè lásán ni ọ̀ràn náà.

      Irú èrò wo ni ó yẹ kí ẹni tí a ṣe láìfí sí náà ní? Ó ha níláti gbìyànjú láti tẹ́ Kristian arákùnrin rẹ̀ lógo kí ó sì fẹ́ kí ó rẹ̀ araarẹ̀ sílẹ̀ bí? Lójú ìwòye ìmọ̀ràn Jesu, àwọn Kristian kò níláti yára láti dẹ́bi fún àwọn arákùnrin wọn. Bí olùrélànàkọjá náà bá gba àṣìṣe rẹ̀, tí ó tọrọ àforíjì, tí ó sì gbìyànjú láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀ràn, ẹni ti a ṣẹ̀ sí náà yóò ti “mú arákùnrin rẹ̀ bọ̀sípò.”​—⁠Matteu 18:⁠15.

  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | July 15
    • Ṣíṣeéṣe náà pé kí a yọ oníwà-àìtọ́ kan tí kò ronúpìwàdà lẹ́gbẹ́ fihàn pé Matteu 18:​15-⁠17 kò níí ṣe pẹ̀lú àwọn aáwọ̀ tí kò tó nǹkan. Jesu ń tọ́kasí àwọn láìfí tí ó wúwo, síbẹ̀ tí ó jẹ́ irú èyí tí a lè yanjú láàárín àwọn ẹni méjì tí ọ̀ràn kan náà. Fún àpẹẹrẹ, láìfí náà lè jẹ́ ìfọ̀rọ̀ èké banijẹ́, tí ó nípa lórí ìfùsì ẹni náà lọ́nà lílekoko. Tàbí ó lè níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn ìnáwó, nítorí pé àwọn ẹsẹ tí ó tẹ̀lé e ní àkàwé Jesu nípa ẹrú aláìláàánú tí a dárí gbèsè ńláǹlà jì nínú. (Matteu 18:​23-⁠35) Ẹ̀yáwó kan tí a kò san padà ní àkókò wulẹ̀ lè jẹ́ ìṣòro kan tí ó rọrùn láti gbójúfòdá tí a lè tètè yanjú láàárín àwọn ènìyàn méjì. Ṣùgbọ́n ó lè di ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ìyẹn ni, olè jíjà, bí ayáwó náà bá fi oríkunkun kọ̀ láti san gbèsè tí ó jẹ padà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́