ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣafarawe Aanu Ọlọrun Lonii
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • 2. Iru imọran wo ni Jesu fifunni ni Matiu 18:15-17 nipa bi a ṣe nilati bojuto ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo?

      2 Bibeli fun wa ni ijinlẹ oye nipa ironu Ọlọrun, koda lori iru awọn ọran bii ohun ti awa nilati ṣe bi ẹnikan ba dẹṣẹ lodi si wa. Jesu sọ fun awọn apọsteli rẹ̀, awọn ti yoo di alaboojuto Kristian lẹhin naa pe: “Bi arakunrin rẹ ba da ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ ṣí ariwisi rẹ̀ paya laaarin iwọ ati oun nikan. Bi o ba fetisilẹ si ọ, iwọ ti jèrè arakunrin rẹ.” Iwa aitọ naa ti o mulọwọ nihin-in kii wulẹ ṣe aṣiṣe ara ẹni ṣakala kan ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo, iru bii jìbìtì tabi ibanijẹ. Jesu wi pe bi igbesẹ yii ko ba yanju ọran naa ti awọn ẹlẹrii ba si wa larọọwọto, ẹni naa ti a ṣẹ̀ si nilati mu wọn dani lọ lati fi ẹ̀rí hàn pe ohun kan wà tí kò tọ́. Eyi ha jẹ igbesẹ ikẹhin ti a lè gbé bi? Bẹẹkọ. “Bi [ẹlẹṣẹ naa] ko ba fetisilẹ si wọn, sọ fun ijọ. Bi oun ko ba fetisilẹ si ijọ paapaa, jẹ ki o dabi eniyan awọn orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode kan si ọ.”—Matiu 18:15-17, NW.

      3. Ki ni ohun ti Jesu nilọkan nigba ti o wi pe alaitọ kan ti kò ronupiwada nilati dabi “eniyan awọn orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode kan”?

      3 Nitori pe Juu ni wọn, awọn apọsteli naa yoo loye ohun ti o tumọsi lati ba ẹlẹṣẹ kan lò “gẹgẹ bi awọn eniyan orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode.” Awọn Juu maa nyẹra fun ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan orilẹ-ede, ti wọn sì koriira awọn Juu ti wọn nṣiṣẹ gẹgẹ bi agbowo ode fun Roomu.a (Johanu 4:9; Iṣe 10:28) Nipa bayii, Jesu ngba awọn ọmọlẹhin naa nimọran pe bi ijọ ba kọ ẹlẹṣẹ kan silẹ, wọn nilati jawọ kikẹgbẹpọ pẹlu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, bawo ni iyẹn ṣe baramu pẹlu wíwà ti Jesu maa ńwà pẹlu awọn agbowo ode ni awọn igba miiran?

  • Ṣafarawe Aanu Ọlọrun Lonii
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • a “Awọn agbowo ode ni pataki ni awujọ awọn Juu ti nbẹ ni Palẹstini tẹmbẹlu fun awọn idi melookan: (1) wọn maa nko owó jọ fun agbara ilẹ okeere ti o gba ilẹ Israẹli, ni titipa bayii ṣe itilẹhin alaiṣe taara fun iwa ika yii; (2) wọn jẹ olokiki buruku alaitẹle ilana iwarere, ti wọn ndi ọlọ́rọ̀ nipasẹ kiko awọn ẹlomiran ti wọn jẹ awọn eniyan wọn tikaraawọn nífà; ati (3) iṣẹ wọn mu ki wọn ni ifarakanra deedee pẹlu awọn Keferi, ti o mu ki wọn di alaimọ niti ọna ijọsin. Ṣiṣaika awọn agbowo ode si ni a ri ninu M[ajẹmu] T[itun] ati iwe itan awọn Juu . . . Ni ibamu pẹlu eyi ti a mẹnukan gbẹhin yii, ikoriira ni a nilati mu gbooro koda si idile agbowo ode.”—The International Standard Bible Encyclopedia.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́