ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 15, 16. (a) Ìgbà wo ni “ẹ̀yìn ìgbà náà” tí ipò nǹkan yóò yí padà fún “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì”? (b) Báwo ni ilẹ̀ tí wọ́n fojú tín-ínrín ṣe wá di èyí táa bọlá fún?

      15 Àpọ́sítélì Mátíù dáhùn ìbéèrè yìí nínú àkọsílẹ̀ onímìísí tó kọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Mátíù ṣàpèjúwe apá ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yẹn pé: “Lẹ́yìn fífi Násárétì sílẹ̀, [Jésù] wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Kápánáúmù lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní àgbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì, kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: ‘Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní ìhà kejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè! àwọn ènìyàn tí ó jókòó nínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá kan, àti ní ti àwọn tí ó jókòó ní ẹkùn ilẹ̀ òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀ là sórí wọn.’”—Mátíù 4:13-16.

  • A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • “Ìmọ́lẹ̀ Ńlá” Náà

      17. Báwo ni “ìmọ́lẹ̀ ńlá” ṣe tàn ní Gálílì?

      17 “Ìmọ́lẹ̀ ńlá kan” tí Mátíù sọ pé ó wà ní Gálílì ńkọ́? Inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà náà ló ti fa ìyẹn yọ. Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísáyà 9:2) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, èké àwọn abọ̀rìṣà ti bo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tún wá dá kún un nípa wíwonkoko mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ inú ẹ̀sìn tiwọn, èyí tí wọ́n fi “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀.” (Mátíù 15:6) Àwọn “afọ́jú afinimọ̀nà” táwọn onírẹ̀lẹ̀ ń tọ̀ lẹ́yìn ń kó ìnira àti ṣìbáṣìbo bá wọn. (Mátíù 23:2-4, 16) Nígbà tí Jésù, Mèsáyà, fara hàn, ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírẹ̀lẹ̀ là lọ́nà ìyanu. (Jòhánù 1:9, 12) Ńṣe ló ṣe wẹ́kú bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe iṣẹ́ tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn ìbùkún ìràpadà rẹ̀, pé wọ́n jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ńlá” náà.—Jòhánù 8:12.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́