ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìwọ Ha Ń Ṣe Ìfẹ́-Inú Ọlọrun Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 1
    • “Kí ni ẹ̀yin ń rò? Ọkùnrin kan wà tí ó ní ọmọkùnrin méjì; ó tọ èkínní wá, ó sì wí pé, Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lónìí nínú ọgbà àjàrà mi. Ó sì dáhùn wí pé, Èmi kì yóò lọ: ṣùgbọ́n ó ronú níkẹyìn, ó sì lọ. Ó sì tọ èkejì wá, ó sì wí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ó sì dáhùn wí fún un pé, Èmi ó lọ, baba: kò sì lọ. Nínú àwọn méjèèjì, èwo ni ó ṣe [“ìfẹ́-inú,” NW] baba rẹ̀?”​—⁠Matteu 21:​28-⁠31.

      Ìdáhùn náà ṣe kedere. Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ èrò tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu, àwa yóò fèsì pé, “Èyí èkínní.” Ṣùgbọ́n jìnnà réré sí ohun tí ó ṣeé fojúrí, nípasẹ̀ àpèjúwe yẹn, Jesu ń pè é wá sí àfiyèsí wa pé ṣíṣe ohun tí baba fẹ́ ni ohun tí ó ṣe pàtàkì jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin kejì sọ pé ohun kì yóò lọ, ó lọ níkẹyìn a sì gbóríyìn fún un fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ṣíṣe irú iṣẹ́ títọ́ kan ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà. Ọmọ kejì gbégbèésẹ̀ nípa ṣíṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà baba náà; kò jáde lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà tirẹ̀.

  • Ìwọ Ha Ń Ṣe Ìfẹ́-Inú Ọlọrun Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 1
    • Ta ni ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun lónìí? Lára iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó billion méjì ènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi, mélòó ni ó dàbí ọmọkùnrin inú àkàwé Jesu, tí ó lọ tí ó sì ṣe ìfẹ́-inú baba rẹ̀? Ìdáhùn náà kò nira láti rí. Àwọn ọmọlẹ́yìn tí ń tẹ̀lé ipasẹ̀ Jesu Kristi nítòótọ́ yóò máa ṣe iṣẹ́ tí ó sọ pé wọn yóò ṣe: “A kò lè ṣàìmá kọ́ wàásù ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Marku 13:10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n tó million mẹ́rin àti àbọ̀ kárí ayé, ń wàásù ìhìnrere Ijọba Ọlọrun wọ́n sì ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn taápọntaápọn, ní títọ́ka sí Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìrètí kanṣoṣo tí aráyé ní fún àlàáfíà àti àìléwu. Ìwọ ha ń nípìn-⁠ín lẹ́kùn-⁠ún-⁠rẹ́rẹ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun bí? Ìwọ ha ń wàásù ìhìnrere Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe bí?​—⁠Iṣe 10:42; Heberu 10:⁠7.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́