ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́—2011 | March 1
    • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

      “Ìhìn rere ìjọba yìí . . . ”—MÁTÍÙ 24:14.

      NÍNÚ ìwàásù Jésù Lórí Òkè èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ó gba àdúrà kan tó jẹ́ àwòkọ́ṣe, nínú àdúrà náà, ó bẹ Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti há àdúrà yìí sórí, tí wọ́n sì ń gba àdúrà náà lágbà-tún-gbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé, àdúrà yìí ni “olórí àdúrà táwọn Kristẹni máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìjọsìn.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gba àdúrà yìí lágbà-tún-gbà ni kò mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ tàbí ohun tó máa ṣe nígbà tó bá dé.—Mátíù 6:9, 10.

      Kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Nítorí pé, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó ta kora, tó ń ṣini lọ́nà, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn àlàyé tí kò yéni nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Ẹnì kan kọ̀wé pé, Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ “ohun àrà ọ̀tọ̀ kan, . . . bí ẹnì kan ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó . . . , èrò tí àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin máa ń ní pé àwọn ti rí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ẹlòmíì sọ pé, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni “ìtọ́ni nípa ṣọ́ọ̀ṣì.” Ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tó ń jẹ́, Catechism of the Catholic Church sì sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run ni òdodo àti àlàáfíà àti ìdùnnú nínú Ẹ̀mí Mímọ́.”

      Wàá rí àlàyé tó yéni yékéyéké lójú ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí. Ó kà pé: “Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso ní ọ̀run, yóò fòpin sí gbogbo ìwà ibi, á sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.” Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn.

      Àwọn Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé Lọ́jọ́ Iwájú

      Ìjọba jẹ́ àkóso kan tí ọba kan ń ṣàkóso lé lórí. Jésù Kristi tó ti jíǹde ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ìran tí Ọlọ́run fi han wòlíì Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe gbé Jésù gorí ìtẹ́ ní ọ̀run, Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn [Jésù] ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ọ̀run; ó sì wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé [Jèhófà Ọlọ́run], wọ́n mú un wá, àní sún mọ́ iwájú Ẹni náà. A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.”—Dáníẹ́lì 7:13, 14.

      Ìwé Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé, Ọlọ́run máa fìdí Ìjọba náà múlẹ̀, pé ó máa fòpin sí gbogbo ìṣàkóso èèyàn àti pé, ìjọba náà kò ní bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì. Ìwé Dáníẹ́lì orí kejì ṣàlàyé àlá tí Ọlọ́run jẹ́ kí ọba Bábílónì lá, nínú èyí tó ti rí ère ńlá kan, tó ṣàpẹẹrẹ bí àwọn ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé á ṣe máa gba ìjọba lọ́wọ́ ara wọn. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ àlá náà. Ó sọ pé, “ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́,” “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:28, 44.

      Ọba Ìjọba Ọlọ́run kò ní dá ṣàkóso. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó fi dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ lójú pé, àwọn àtàwọn olóòótọ́ míì máa ní àjíǹde sí ọ̀run, wọ́n sì máa jókòó sórí ìtẹ́. (Lúùkù 22:28-30) Kì í ṣe ìtẹ́ gidi ni Jésù ní lọ́kàn, nítorí nínú ohun tó sọ, ọ̀run ni Ìjọba yẹn máa wà. Bíbélì ṣàlàyé pé àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso máa wá látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” Wọ́n máa jẹ́ “ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.

      Ìdí Tí Ìhìn Nípa Ìjọba Ọlọ́run fi Jẹ́ Ìhìn Rere

      Kíyè sí i pé, Kristi Jésù gba àṣẹ láti ṣàkóso gbogbo “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè,” àwọn tó ń bá Jésù ṣàkóso náà sì máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” Àwọn wo ló máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba yìí? Àwọn ni àwọn tó gbọ́ ìhìn rere tí à ń wàásù lónìí, tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò. Àwọn òkú tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé àtàwọn tó máa láǹfààní láti wà láàyè títí láyé tún wà lára àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà.

      Kedere ni Bíbélì sọ àwọn ìbùkún tí àwọn èèyàn náà máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba náà. Díẹ̀ nìyí lára wọn:

      “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—Sáàmù 46:9.

      “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.

      “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

      “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:5, 6.

      “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè.”—Jòhánù 5:28, 29.

      “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

      Ẹ ò rí i pé ìhìn rere lèyí jẹ́ lóòótọ́! Síwájú sí i, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ fi hàn pé Ìjọba náà máa tó bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso òdodo lé ilẹ̀ ayé lórí.

  • Kí Ni Ìhìn Rere?
    Ilé Ìṣọ́—2011 | March 1
    • Kí Ni Ìhìn Rere?

      “Ìhìn rere ìjọba yìí . . . ”—MÁTÍÙ 24:14.

      ÀWỌN Kristẹni ní láti wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” fún àwọn èèyàn, kí wọ́n sọ fún wọn pé Ìjọba yìí ló máa ṣàkóso gbogbo ayé nínú òdodo lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, a tún lo ọ̀rọ̀ náà, “ìhìn rere” lọ́nà míì nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì tọ́ka sí “ìhìn rere ìgbàlà” (Sáàmù 96:2); “ìhìn rere Ọlọ́run” (Róòmù 15:16); àti “ìhìn rere nípa Jésù Kristi.”—Máàkù 1:1.

      Ní kúkúrú, ìhìn rere ni gbogbo òtítọ́ tí Jésù sọ àtàwọn èyí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ sílẹ̀. Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti sọ nípa Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn, wọ́n tún gbọ́dọ̀ sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.

      Kí làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe nípa ọ̀ràn yìí? Ọ̀pọ̀ ni kò mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, kò sì ní ṣeé ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ìjọba náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó máa mú ara tu àwọn èèyàn nìkan ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń wàásù, irú bí, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Wọ́n tún ń gbìyànjú láti fa àwọn èèyàn sínú ẹ̀sìn wọn nípa ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn èèyàn tàbí nípa kíkọ́ ilé ìwòsàn, iléèwé àti ilé fún àwọn tálákà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn nǹkan yìí lè mú kí àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ sí i, àmọ́ kò lè mú káwọn èèyàn jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tó ń fi gbogbo ọkàn fẹ́ láti mú kí ìgbé ayé wọn bá ẹ̀kọ́ Jésù mu.

      Ọkùnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀sìn sọ pé: “Ṣàṣà làwọn ọ̀mọ̀wé tàbí aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni tó máa sọ pé kò yẹ ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tàbí pé kó yẹ ká ṣe iṣẹ́ tí Jésù ṣe, ká sì kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo ohun tí Jésù sọ. . . . Ó ṣe tán, ìtọ́ni Jésù lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere. Àwa la ò kan ṣe ohun tó ní ká ṣe. A ò fọwọ́ pàtàkì mú un rárá. Ká sòótọ́, ó hàn pé a ò mọ bó ṣe yẹ ká ṣe iṣẹ́ náà.”

      Bákan náà, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, èèyàn mọ́kàndínlógún nínú ogún ló gbà pé ó yẹ káwọn wàásù ìhìn rere nítorí pé, ó wà lára ohun tó fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbàgbọ́. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló gbà pé, ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbà ṣe é ni pé, kí ìgbésí ayé àwọn jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn èèyàn, kì í ṣe pé kí àwọn máa wàásù ohun tí àwọn gbà gbọ́. Obìnrin kan lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé: “Iṣẹ́ ìhìn rere kì í ṣe ọ̀ràn kéèyàn kàn máa wàásù ṣáá. Àwa fúnra wa la ní láti jẹ́ Ìhìn Rere.” Ìwé ìròyìn U.S. Catholic, tó ṣe ìwádìí yìí sọ pé, ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ wàásù ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nítorí “ẹ̀bi ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì wọn jẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí àti nítorí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí kò yéni.”

      Bíṣọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kan tún kédàárò pé, ohùn àwọn tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kò ṣọ̀kan, wọn kò sì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọn kò ní ìgboyà láti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ọ̀nà ìgbésí ayé wọn kò sì yàtọ̀ sí táwọn èèyàn tí kò mọ Ọlọ́run. Ó wá fi ìbànújẹ́ béèrè pé: “Àwọn wo gan-an ló kúnjú ìwọ̀n láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà báyìí?”

      Bíṣọ́ọ̀bù yìí kò dáhùn ìbéèrè tó béèrè yẹn. Àmọ́ ìdáhùn wà. Wàá rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

      [Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

      Ìhìn rere jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́