-
Àwọn Wo Ló Ń Wàásù Ìhìn Rere Náà?Ilé Ìṣọ́—2011 | March 1
-
-
Àwọn Wo Ló Ń Wàásù Ìhìn Rere Náà?
“A ó sì wàásù . . . ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—MÁTÍÙ 24:14.
ÀWỌN Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe é. Ọ̀nà kan ni . . .
Ọ̀rọ̀ Ẹnu. Bíi ti Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. (Lúùkù 8:1; 10:1) Wọn kò retí pé káwọn èèyàn wá bá àwọn. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù méje kárí ayé máa ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé, lójú ọ̀nà, lórí tẹlifóònù àti láwọn ọ̀nà míì. Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ yìí.
Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n tún ń kọ́ àwọn èèyàn ní “gbogbo ohun tí [Jésù] ti pa láṣẹ.” (Mátíù 28:20) Wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ní igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀. Wọ́n ń wàásù fún onírúurú èèyàn tí ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra. Wọ́n ń wàásù láwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ìlú, nínú igbó àgbègbè Amazon nílẹ̀ Brazil àti nínú igbó àwọn ará Siberia, ní àwọn aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà àti lórí àwọn Òkè Himalaya nílẹ̀ Éṣíà. Wọn kì í gba owó fún gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń lo owó àti àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà, ìyẹn sì jẹ́ nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn. Wọ́n tún ń wàásù ìhìn rere nípasẹ̀ . . .
Àwọn Ìtẹ̀jáde. Àkọlé ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí sọ pé, Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà, ní báyìí èdè igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [185] la fi ń tẹ̀ ẹ́, a sì ń tẹ ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù méjìlélógójì [42,000,000] jáde lẹ́ẹ̀kan. Ìwé ìròyìn kan tún wà tó ṣèkejì èyí, Jí! lorúkọ rẹ̀, òun náà ń kéde Ìjọba Ọlọ́run, èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] la fi ń tẹ̀ ẹ́, a sì ń tẹ ẹ̀dà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì mílíọ̀nù [40,000,000] jáde lẹ́ẹ̀kan.
Wọ́n ń ṣe àwọn ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú, àwọn àwo CD àti MP3 àtàwọn àwo DVD tó ṣàlàyé nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì wà ní èdè tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogójì [540]. Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan yìí jáde, wọ́n sì ti fún àwọn èèyàn ní iye tó lé ní ogún bílíọ̀nù lára rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ ìpíndọ́gba ẹ̀dà mẹ́ta fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà lórí ilẹ̀ ayé!
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti tẹ Bíbélì jáde ní onírúurú èdè tàbí kí wọ́n gbé é fún àwọn èèyàn láti tẹ̀ ẹ́ jáde. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àwọn ló tẹ̀ ẹ́ jáde, àwọn náà ló sì ń mú un lọ fún àwọn èèyàn nílé wọn, ní báyìí Bíbélì yìí ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96]. Wọ́n ti pín ẹ̀dà tó lé ní igba mílíọ̀nù ó dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [166,000,000] Bíbélì yìí fún àwọn èèyàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà . . .
Ní Àwọn Ìpàdé. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe ìpàdé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò wọn, àwọn ìpàdé náà kì í ṣe ààtò ẹ̀sìn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n wà fún. Wọ́n máa ń sọ àsọyé tí wọ́n mú jáde látinú Bíbélì, wọ́n sì máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde míì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn ìpàdé náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè di ọ̀jáfáfá nídìí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.
Ohun kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ìjọ wọn kárí ayé tí iye wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé méje [107,000], èyí sì ń mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn. Gbogbo èèyàn ni ìpàdé yìí wà fún. Wọn kì í gbé igbá owó. Àmọ́ ṣá o, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo èyí máa já sí, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bá fi ohun tí wọ́n ń wàásù ṣèwàhù. Nítorí náà, wọ́n ń wàásù ìhìn rere nípasẹ̀ . . .
Ìwà Wọn. Wọ́n ń sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìwà wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn èèyàn máa ṣe sí wọn, ni wọ́n ń ṣe sí àwọn èèyàn. (Mátíù 7:12) Bí wọ́n tílẹ̀ jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì máa ń ṣe àṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo ọkàn ni wọ́n fi fẹ́ láti rí i pé àwọn ń hùwà tó fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn, kì í ṣe nípa wíwàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn nìkan, àmọ́ wọ́n tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì nígbà tó bá ṣeé ṣe.
Kì í ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ fi ìwàásù wọn yí gbogbo ayé pa dà o! Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ti ṣe iṣẹ́ náà dé ibi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, òpin máa dé gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ. Kí ni àbájáde èyí máa jẹ́ fún ayé àtàwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere náà kárí ayé
-
-
Kí Ni “Òpin” Náà?Ilé Ìṣọ́—2011 | March 1
-
-
Kí Ni “Òpin” Náà?
“. . . nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—MÁTÍÙ 24:14.
LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ nípa òpin ayé. Ìwé, sinimá àtàwọn ìwé ìròyìn, títí kan àwọn aláwàdà àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti ṣàlàyé bí ìparun ayé ṣe máa dé. Wọ́n ní ogun runlérùnnà máa mú ìparun bá ayé, pé àwọn òbìrìkìtì kan tí wọ́n ń pè ní steroid máa kọ lura, pé àwọn kòkòrò àrùn tó ń ṣekú pani máa gbayé kan, pé ojú ọjọ́ á máa yí pa dà lódìlódì tàbí pé ohun kan máa já lu ayé.
Èrò àwọn ẹlẹ́sìn náà yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀pọ̀ wọn ló ń kọ́ni pé, “òpin” náà máa pa gbogbo ohun alààyè àti ilẹ̀ ayé run pátápátá. Nígbà tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ń ṣàlàyé ìwé Mátíù 24:14, ó sọ ohun tó bani lẹ́rù yìí pé: “Ẹsẹ yìí jẹ́ ọ̀kan lára apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ìran wa yìí dojú kọ ìparun yán-án-yán, àmọ́ àwọn èèyàn díẹ̀ ló rí àgbákò tó ń bọ̀ náà.”
Àwọn tó ní irú èrò yìí ti gbàgbé òtítọ́ kan tó ṣe pàtàkì pé, Jèhófà Ọlọ́run ti “fìdí [ilẹ̀ ayé] múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, . . . kò wulẹ̀ dá a lásán, [àmọ́] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń sọ nípa “òpin” náà, kò ní in lọ́kàn pé ayé yìí máa pa run, kò sì ní in lọ́kàn pé, ẹ̀dá èèyàn máa pa run. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé, àwọn èèyàn burúkú ló máa pa run, ìyẹn àwọn tó kọ̀ jálẹ̀ láti máa gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó bá àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà mu.
Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò. Ká ní o ní ilé kan tó jojú ní gbèsè, tó o sì ní káwọn èèyàn máa gbé ibẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn kan lára àwọn tó gbé ibẹ̀ ń gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn yòókù, wọ́n sì ń bójú tó ilé rẹ. Àmọ́, oníwàhálà làwọn yòókù, wọ́n máa ń bá ara wọn jà, wọ́n sì máa ń bú àwọn èèyàn rere tó ń gbe ibẹ̀. Àwọn oníwàhálà yìí ba àwọn ohun ìní rẹ jẹ́, nígbà tó o sì sọ fún wọn, ńṣe ni wọn ń bá ìwàkiwà wọn nìṣó.
Kí lo máa ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà? Ṣé wàá wó ilé rẹ ni? Ó jọ pé o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wàá lé àwọn èèyàn burúkú náà kúrò nílé rẹ tí wàá sì ṣàtúnṣe ohun tí wọ́n ti bà jẹ́.
Ohun tí Jèhófà máa ṣe nìyẹn. Ó mí sí onísáàmù yìí láti kọ̀wé pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:9-11.
Àpọ́sítélì Pétérù náà sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” (2 Pétérù 3:5, 6) Ìkún Omi ọjọ́ Nóà ni àpọ́sítélì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ló pa run, àmọ́ ilẹ̀ ayé kò pa run. Àkúnya Omi tó kárí ayé yìí jẹ́ “àpẹẹrẹ kan . . . fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.”—2 Pétérù 2:6.
Pétérù wá fi kún un pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” Tá a bá ní ká dúró sí ibẹ̀ yẹn, a lè ṣi ọ̀rọ̀ náà lóye pátápátá. Àmọ́ kíyè sí i pé ẹsẹ náà ń bá a nìṣó pé: “Àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Kì í ṣe ilẹ̀ ayé ló máa pa run bí kò ṣe àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Kí ló wá máa tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Pétérù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun [Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà máa ṣàkóso] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ ẹ̀dá èèyàn olódodo] wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:7, 13.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tún fi hàn pé àkókò tí “òpin” náà máa dé ti sún mọ́lé. Ka Mátíù 24:3-14 àti 2 Tímótì 3:1-5 láti rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.a
Ǹjẹ́ kò yà ẹ́ lẹ́nu pé, àwọn èèyàn kò lóye Mátíù 24:14, ẹsẹ Bíbélì tí ọmọdé pàápàá lè lóye? Ìdí wà tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀. Sátánì ti fọ́ èrò inú àwọn èèyàn lójú, kí wọ́n má bàa lóye òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bákan náà, Ọlọ́run ti fi àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe pa mọ́ fún àwọn agbéraga, ó sì ti ṣí wọn payá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Gbọ́ ohun tí Jésù sọ lórí èyí, ó ní: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Ẹ ò rí i bó ti jẹ́ ohun iyì tó pé, a wà lára àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó lóye ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, tá a sì tún wà lára àwọn tó lè máa retí ìbùkún tó máa mú wá fún àwọn tó tì í lẹ́yìn!
-