ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ibo Ni A Ti Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́—1997 | March 15
    • Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù Kristi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba àwọn ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Jésù tún sọ pé: ‘Ẹ máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.’—Lúùkù 12:15.

  • Ibo Ni A Ti Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́—1997 | March 15
    • Nínú wíwá tí wọ́n ń wá ayọ̀ kiri, àwọn mìíràn ń yíjú sí ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, nípa gbígbìyànjú láti mú ọ̀wọ̀ ara ẹni wọn pọ̀ sí i. Àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é kún inú àwọn ilé ìkówèésí àti ilé ìtàwé, ṣùgbọ́n irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ kò tí ì mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá fún àwọn ènìyàn. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, níbo ni a ti lè rí ojúlówó ayọ̀?

      Láti lè láyọ̀ ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí tí a ti dá mọ́ wa. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí jẹ lọ́kàn.” Dájúdájú, kì yóò ṣe wá ní àǹfààní kankan bí a bá mọ àìní yìí, tí a sì kùnà láti ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀. Láti ṣàkàwé: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí eléré ẹlẹ́mìí ẹṣin kan, tí kò mu omi tí ara rẹ̀ ń fẹ́, lẹ́yìn eré ìje náà? Òun kò ha ní pàdánù omi ara, kí ó sì jìyà àwọn àbájáde eléwu mìíràn láìpẹ́ bí? Lọ́nà kan náà, bí a kò bá tẹ́ àìní wa fún oúnjẹ tẹ̀mí lọ́rùn, a óò rọ nípa tẹ̀mí nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Èyí yóò yọrí sí pípàdánù ìdùnnú àti ayọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́