ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | May 1
    • 8, 9. (a) Ki ni wíwàníhìn-ín Jesu bi ọba ni ninu? (b) Ki ni asọtẹlẹ Jesu ti o niiṣe pẹlu awọn èké Kristi fihàn nipa ibi ti yoo dé si ati ọ̀nà ti yoo gbà wàníhìn-ín?

      8 Niwọn bi ipo-ọba Jesu ti ni gbogbo ayé ninu, ijọsin tootọ ń gbooro ni gbogbo agbaye. Wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba (pa·rou·siʹa) jẹ́ akoko ayẹwo kaakiri agbaye. (1 Peteru 2:12) Ṣugbọn olu-ilu nla, tabi aarin gbungbun kan, nibi ti a ti lè lọ bá Jesu ha wà bi? Jesu dahun eyi nipa sisọ asọtẹlẹ pe ni ifojusọna fun wíwàníhìn-ín rẹ̀, awọn èké Kristi yoo dide. O kilọ pe: “Nitori naa bi wọn ba wi fun yin pe, Wò ó, ó [Kristi] wa ni aginju; ẹ má lọ sibẹ: Wò ó, ó wà ní ìyẹ̀wù; ẹ maṣe gbagbọ. Nitori gẹgẹ bi manamana tii kọ lati ila-oorun, tii sii mọlẹ dé iwọ-oorun; bẹẹ ni [wíwàníhìn-ín, NW] [pa·rou·siʹa] Ọmọ eniyan yoo rí pẹlu.”—Matteu 24:24, 26, 27.

  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | May 1
    • 10. Bawo ni ìmọ́lẹ̀ otitọ Bibeli ṣe ń tàn kaakiri agbaye?

      10 Kaka bẹẹ, kì yoo si ohun kan lati fi pamọ nipa ti dídé Jesu gẹgẹ bi Ọba, ni ibẹrẹ wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba. Gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ, ni ọ̀nà kari-aye, awọn ìmọ́lẹ̀ otitọ Bibeli ń baa lọ lati maa tàn yika agbegbe ti o gbooro lati ayika ila-oorun de ayika iwọ-oorun. Loootọ, gẹgẹ bi awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ode-oni, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi araawọn hàn bi “ìmọ́lẹ̀ awọn keferi, ki [Jehofa] lè ṣe igbala . . . titi de opin ayé.”—Isaiah 49:6.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́