ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sọ Fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
    • 16. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rin míì wo ló tún sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jésù máa dé?

      16 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀.” Nínú àkàwé nípa àwọn wúńdíá, Jésù sọ pé: “Bí wọ́n tí ń lọ láti rà á, ọkọ ìyàwó dé.” Nínú àkàwé nípa tálẹ́ńtì, Jésù sọ pé: “Lẹ́yìn àkókò gígùn, ọ̀gá ẹrú wọnnì dé.” Nínú àkàwé yìí kan náà, ọ̀gá náà sọ pé: “Nígbà tí mo bá sì dé, èmi ì bá wá gba ohun tí ó jẹ́ tèmi.” (Mát. 24:46; 25:10, 19, 27) Ìgbà wo ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ń tọ́ka sí?

      17. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìgbà wo la sọ pé Jésù dé, bó ṣe wà nínú Mátíù 24:46?

      17 Tẹ́lẹ̀ rí, a ti sọ nínú àwọn ìwé wa pé ìgbà tí Jésù wá tàbí tí ó dé ní ọdún 1918 ni àwọn ibi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ń sọ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Ka Mátíù 24:45-47.) Báwo la ṣe lóye ìgbà tí Jésù dé, bó ṣe wà ní ẹsẹ 46? A gbà tẹ́lẹ̀ pé ọdún 1918 ni Jésù “dé” láti wá wo bí ipò tẹ̀mí àwọn ẹni àmì òróró ṣe rí àti pé ọdún 1919 ló yan ẹrú náà sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá rẹ̀. (Mál. 3:1) Àmọ́, nígbà tá a tún gbé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí yẹ̀ wò, a wá rí i pé ìgbà tá a rò pé ó ṣẹ kọ́ ló ṣẹ. Ó pọn dandan nígbà náà pé ká tún ojú ìwòye wa ṣe. Kí nìdí?

      18. Ibo la máa parí èrò sí tá a bá ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Jésù látòkèdélẹ̀ nípa ìgbà tó máa dé?

      18 Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú Mátíù 24:46, gbogbo ìgbà tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “dé” ló fi ń tọ́ka sí ìgbà tóun máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, tó sì máa fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n nígbà ìpọ́njú ńlá. (Mát. 24:30, 42, 44) Bákan náà, bá a ṣe ṣàlàyé ní ìpínrọ̀ 12, ìgbà ìpọ́njú ńlá yìí kan náà ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé òun máa “dé” nínú Mátíù 25:31, ìyẹn ìgbà tó máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti parí èrò sí pé ọjọ́ iwájú tí Jésù máa dé, ìyẹn nígbà ìpọ́njú ńlá náà ló máa yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀, bó ṣe wà nínú Mátíù 24:46, 47.f Kò sí àní-àní pé bá a ṣe ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Jésù látòkèdélẹ̀ mú kó ṣe kedere pé ọjọ́ iwájú tí Jésù máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ni àwọn ibi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn nígbà ìpọ́njú ńlá.

  • Sọ Fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
    • e Ìpínrọ̀ 15: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní erʹkho·mai la túmọ̀ sí “dé”, ohun kan náà la sì túmọ̀ sí “ń bọ̀.”

      f Ìpínrọ̀ 18: Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “tí ó bá dé” nínú Mátíù 24:46 náà la túmọ̀ sí “ń bọ̀” nínú Mátíù 24:30, 42, 44.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́