-
“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”Ilé Ìṣọ́—2012 | September 15
-
-
“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” —MÁT. 25:13.
-
-
“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”Ilé Ìṣọ́—2012 | September 15
-
-
1-3. (a) Ipò wo la lè fi ṣàpèjúwe kókó pàtàkì tó wà nínú méjì lára àwọn àkàwé Jésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká dáhùn?
JẸ́ KÁ sọ pé aláṣẹ kan ní kó o fi ọkọ̀ gbé òun lọ síbi ìpàdé pàtàkì kan. Àmọ́, nígbà tó ku ìṣẹ́jú bíi mélòó kan kó o lọ gbé e, o wá rí i pé epo tó wà nínú ọkọ̀ yẹn kò lè gbé e yín débi tí ẹ̀ ń lọ. O wá sáré lọ ra epo díẹ̀. Ṣùgbọ́n bó o ṣe lọ báyìí ni aláṣẹ náà dé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹ, àmọ́ kò rí ẹ. Nígbà tí kò lè dúró mọ́, ó pe ẹlòmíì pé kó gbé òun lọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lo pa dà dé láti ibi tó o ti lọ ra epo, o wá rí i pé aláṣẹ yẹn ti fi ẹ́ sílẹ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ?
2 Wàyí o, jẹ́ ká sọ pé ìwọ ni aláṣẹ náà, o sì yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó jáfáfá láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan. O ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, wọ́n sì gbà láti ṣe é. Ṣùgbọ́n, nígbà tó ṣe díẹ̀ tó o pa dà dé, o wá rí i pé àwọn méjì ló ṣe iṣẹ́ wọn. Èyí tí kò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sì tún wá ń ṣe àwáwí. Kò tiẹ̀ fọwọ́ kan iṣẹ́ náà rárá. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ?
3 Nínú àkàwé nípa àwọn wúńdíá àti tálẹ́ńtì, Jésù lo irú ipò tó wà nínú àwọn àpèjúwe méjì yìí láti ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé nígbà ìkẹyìn, àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró máa jẹ́ olóòótọ́ àti olóye tí àwọn yòókù kò sì ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.a (Mát. 25:1-30) Ó sọ kókó pàtàkì tó fẹ́ fà yọ, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà,” ìyẹn, àkókò náà gan-an tí Jésù máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí ayé Sátánì. (Mát. 25:13) Àwa náà gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lónìí. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ṣíṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fún wa ní ìṣírí pé ká ṣe? Àwọn wo ló ti fi hàn pé àwọn ti ṣe tán láti là á já? Kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe báyìí ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
-