ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
    • 21 Ṣùgbọ́n, báwo ni nǹkan yóò ti rí fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a ṣèwádìí nínú òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀.”—Matteu 25:31, 32.

      22, 23. Àwọn kókó wo ni ó fi hàn pé òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ kò bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ ní 1914?

      22 Òwe àkàwé yìí ha ní í ṣe pẹ̀lú 1914, nígbà tí Jesu jókòó nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ọba, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí? Tóò, Matteu 25:34 sọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba, nítorí náà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, òwe àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà tí Jesu ti di Ọba ní 1914. Ṣùgbọ́n ìdájọ́ wo ni ó ṣe ní kété lẹ́yìn náà? Kì í ṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ń sọ pé àwọn para pọ̀ jẹ́ “ilé Ọlọrun.” (1 Peteru 4:17) Ní ìbámu pẹ̀lú Malaki 3:1-3, Jesu, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Jehofa, bẹ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí ó ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ ayé wò láti ṣèdájọ́ wọn. Ó tún jẹ́ àkókò fún ìdájọ́ lórí Kristẹndọmu, tí ó fi èké jẹ́wọ́ pé òún jẹ́ “ilé Ọlọrun.”c (Ìṣípayá 17:1, 2; 18:4-8) Síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tí ó fi hàn pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, tàbí láti ìgbà náà wá, Jesu ti jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́.

      23 Bí a bá ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbòkègbodò Jesu nínú òwe àkàwé náà, a óò rí i pé, ó ṣèdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Òwe àkàwé náà kò fi hàn pé irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a nìṣó fún sáà gígùn ọlọ́dún púpọ̀, bí ẹni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń kú ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá wọ̀nyí ni a ti ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ fún ikú àìnípẹ̀kun tàbí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ti kú ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti lọ sí isà okú ti gbogbo aráyé. (Ìṣípayá 6:8; 20:13) Ṣùgbọ́n, òwe àkàwé náà ń ṣàpèjúwe àkókò náà nígbà tí Jesu ń ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n wà láàyè nígbà náà, tí wọ́n sì dojú kọ ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
    • “Oun yoo sì ya awọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn kan tí ń ya awọn àgùtàn sọ́tọ̀ kúrò lára awọn ewúrẹ́.”—MATTEU 25:32.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
    • 3. Ṣáájú nínú ìjíròrò rẹ̀, kí ni Jesu sọ pé yóò jẹ yọ kété lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá náà bá ti bẹ̀rẹ̀?

      3 Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apàfiyèsí tí yóò ṣẹlẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn” ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń retí. Ó wí pé, nígbà náà ni “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn” yóò fara hàn. Èyí yóò nípa jíjinlẹ̀ lórí “gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé” tí wọn yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.” Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wà pẹ̀lú “awọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Matteu 24:21, 29-31)a Kí ni nípa ti òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́? Àwọn Bibeli òde òní fi í sí orí 25, ṣùgbọ́n ó jẹ́ apá kan èsì Jesu, tí ó pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé síwájú sí i nípa bíbọ̀ rẹ̀ nínú ògo, tí ó sì darí àfiyèsí sórí ṣíṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.”—Matteu 25:32.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́