ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ọgbà yìí tura gan-an ni, àwọn igi ólífì sì wà níbẹ̀. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débẹ̀, Jésù fi mẹ́jọ lára wọn síbì kan, bóyá níbi àbáwọlé ọgbà náà. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.” Jésù wá wọnú ọgbà náà, ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání. Ìdààmú bá a gan-an, ó wá sọ fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”—Mátíù 26:36-38.

  • Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Àtìgbà tí Jésù ti wà lọ́run ló ti ń rí bí ìjọba Róòmù ṣe máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń pa wọ́n nípa ìkà. Ní báyìí tó ti di èèyàn, ó dájú pé ó ti mọ bí ìyà ṣe ń rí lára, ó sì mọ̀ pé ìyà kì í ṣomi ọbẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ló gbà á lọ́kàn, ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ló ń rò. Ẹ̀dùn ọkàn bá a bó ṣe ń rò ó pé wọ́n máa pa òun bí ọ̀daràn, ìyẹn sì lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Baba òun. Ní wákàtí díẹ̀ sígbà yẹn, wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wọ́n sì máa gbé e kọ́ sórí òpó igi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́