ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo La Ṣe Ń Wàásù Ìhìn Rere?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 21. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì dúró síbi kẹ̀kẹ́ ìpàtẹ ìwé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ọkùnrin kan sì ń bá wọn sọ̀rọ̀.

      Ẹ̀KỌ́ 21

      Báwo La Ṣe Ń Wàásù Ìhìn Rere?

      Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Ìròyìn ayọ̀ tó yẹ kí gbogbo èèyàn gbọ́ ni. Jésù fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun sọ ìròyìn náà fún gbogbo èèyàn! (Mátíù 28:19, 20) Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe ohun tí Jésù sọ yìí?

      1. Báwo ni ohun tó wà ní Mátíù 24:14 ṣe ń ṣẹ lóde òní?

      Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Mátíù 24:14) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn láti máa ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí. À ń wàásù ìhìn rere yìí kárí ayé ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ! Iṣẹ́ ńlá ni iṣẹ́ yìí o! Ó gba àkókò àti okun, ó sì gba pé ká ṣètò ẹ̀ dáadáa. A ò lè ṣe iṣẹ́ náà láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.

      2. Àwọn nǹkan wo là ń ṣe ká lè rí i pé a ń wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn?

      A máa ń wàásù níbikíbi tá a bá ti lè rí àwọn èèyàn. Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, a máa ń wàásù “láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 5:42) Ọ̀nà tá à ń gbà wàásù yìí ń jẹ́ ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́dọọdún. Nítorí pé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ sí nílé, a tún máa ń wàásù láwọn ibòmíì tá a ti lè rí wọn. A máa ń lo gbogbo àǹfààní tá a bá rí láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fáráyé.

      3. Ojúṣe àwọn wo ni láti máa wàásù ìhìn rere?

      Ojúṣe gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ni láti máa wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. Ọwọ́ pàtàkì la fi mú iṣẹ́ yìí. A máa ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wàásù fáwọn èèyàn torí a fẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà. (Ka 1 Tímótì 4:16.) A kì í gba owó nídìí iṣẹ́ yìí nítorí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:7,8) Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tá à ń wàásù. Àmọ́, a kì í jẹ́ kó sú wa, torí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jẹ́ ara ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Jèhófà, ó sì ń múnú rẹ̀ dùn.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti wàásù kárí ayé àti bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.

      A. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù fún ọkùnrin kan tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè kan tí koríko bò ní Costa Rica. B. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù fún àwọn apẹja ní èbúté kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà. D. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù fún ọkùnrin kan ní abúlé kan lórílẹ̀-èdè Benin. E. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń wàásù fún obìnrin kan ní ọjà orí omi nílẹ̀ Thailand. Ẹ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù fún obìnrin kan níwájú òkúta fífẹ̀ kan tó wà ní erékùṣù Yap. F. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì nílẹ̀ Sweden ń wàásù fún obìnrin kan tó dúró sójú ọ̀nà tí yìnyín bò, odò kan sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà náà.

      À ń wàásù kárí ayé: (A) Costa Rica, (B) Amẹ́ríkà, (D) Benin, (E) Thailand, (Ẹ) Erékùṣù Yap, (F) Sweden

      4. À ń ṣiṣẹ́ kára láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn níbi gbogbo. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Wíwàásù ní “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé” (7:33)

      • Kí ló wú ẹ lórí nípa ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láti rí i pé àwọn wàásù fáwọn èèyàn?

      Ka Mátíù 22:39 àti Róòmù 10:13-​15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa?

      • Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń wàásù ìhìn rere?​—Wo ẹsẹ 15.

      5. À ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run

      Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ New Zealand arákùnrin kan tó ń jẹ́ Paul bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé lọ́sàn-án ọjọ́ kan. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, obìnrin náà ti gbàdúrà pé kí ẹnì kan wá sọ́dọ̀ òun, ó sì lo Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run nínú àdúrà rẹ̀. Paul sọ pé, “Wákàtí mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo dé ẹnu ọ̀nà ilé obìnrin náà.”

      Ka 1 Kọ́ríńtì 3:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ New Zealand ṣe fi hàn pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù wa?

      Ka Ìṣe 1:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

      Ǹjẹ́ o mọ̀?

      Ní ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀, a máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ́ ká lè wàásù. Tó bá jẹ́ pé o ti lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé náà, kí lo lè sọ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà níbẹ̀?

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wà nípàdé ìjọ, wọ́n ń ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe máa wàásù fáwọn èèyàn.

      6. Àṣẹ Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé bá a ṣe ń wàásù

      Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn alátakò gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń ṣe dúró. Àmọ́, àwọn Kristẹni yẹn ‘fìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà tó bófin mu’ kí wọ́n lè jà fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti wàásù. (Fílípì 1:7) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun kan náà lónìí.a

      Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: A Ń Gbèjà Ìhìn Rere Lọ́nà Tó Bófin Mu (2:28)

      Ka Ìṣe 5:27-42, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tá ò fi ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?​—Wo ẹsẹ 29, 38 àti 39.

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń wàásù láti ilé dé ilé?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun láti máa ṣe iṣẹ́ yìí.

      Kí lo rí kọ́?

      • Àwọn wo ló ń wàásù ìhìn rere kárí ayé?

      • Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

      • Ṣé o rò pé iṣẹ́ ìwàásù lè fúnni láyọ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn láwọn ìlú ńlá.

      A Wàásù Lákànṣe Láwọn Ibi Térò Pọ̀ Sí Nílùú Paris (5:11)

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kí wọ́n lè wàásù fún àwọn tí ogun tàbí àwọn ìṣòro míì lé kúrò nílùú wọn.

      Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Òùngbẹ Tẹ̀mí Ń Gbẹ (5:59)

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó ń mú kí obìnrin kan láyọ̀ bó ṣe ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.

      Mo Láyọ̀ Pé Mo Yan Ohun Tí Ó Tọ́ (6:29)

      Ka ìwé yìí kó o lè rí báwọn ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre, tí ìyẹn sì ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà tẹ̀ síwájú.

      “Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́” (Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, orí 13)

      a Ọlọ́run ló pàṣẹ pé ká máa wàásù. Torí náà, kò sídìí fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ayé ká tó lè wàásù ìhìn rere.

  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 23. Wọ́n ń ṣe ìrìbọmi fún obìnrin kan kó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ńṣe ni wọ́n rì í bọnú omi pátápátá.

      Ẹ̀KỌ́ 23

      Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!

      Jésù kọ́ wa pé ó pọn dandan káwọn tó bá fẹ́ di Kristẹni ṣèrìbọmi. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Àmọ́, kí ni ìrìbọmi? Kí sì ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?

      1. Kí ni ìrìbọmi?

      Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ìrìbọmi túmọ̀ sí “rì bọ” inú omi. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jòhánù rì í bọ inú Odò Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, ó “jáde látinú omi.” (Máàkù 1:9, 10) Lọ́nà kan náà, tí àwa Kristẹni tòótọ́ bá fẹ́ ṣèrìbọmi, ńṣe la máa ń ri ẹni náà bọ inú omi pátápátá.

      2. Kí lẹni tó ṣèrìbọmi ń fi hàn?

      Tẹ́nì kan bá ṣèrìbọmi, ńṣe lonítọ̀hún ń fi hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Báwo la ṣe ń ṣe ìyàsímímọ́? Kẹ́nì kan tó ṣèrìbọmi, ó máa kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà lóun nìkan, á sì sọ fún un pé ó wu òun láti máa sìn ín títí ayé. Ó máa ṣèlérí pé Jèhófà nìkan lòun á máa sìn àti pé ìfẹ́ Jèhófà lòun á fi sí ipò àkọ́kọ́ láyé òun. Ó máa pinnu pé ‘òun á sẹ́ ara òun, òun á sì máa tẹ̀ lé’ àwọn ẹ̀kọ́ àti àpẹẹrẹ Jésù. (Mátíù 16:24) Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi yìí máa jẹ́ kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

      3. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?

      Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, ó ṣe pàtàkì pé kó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó o sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀. (Ka Hébérù 11:6.) Bí ìmọ̀ rẹ ṣe ń pọ̀ sí i, tí ìgbàgbọ́ rẹ sì ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó dájú pé á máa wù ẹ́ láti sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà, wàá sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ. (2 Tímótì 4:2; 1 Jòhánù 5:3) Tó o bá ti ń gbé ìgbé ayé rẹ “lọ́nà tó yẹ Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún,” o lè pinnu láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.​—Kólósè 1:9, 10.a

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Wo ohun tó o lè kọ́ nínú ìrìbọmi Jésù àtàwọn nǹkan tó yẹ kẹ́nì kan ṣe tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi.

      4. Ohun tá a rí kọ́ nínú ìrìbọmi Jésù

      Ka Mátíù 3:13-17 kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìrìbọmi Jésù. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé ọmọ ọwọ́ ni Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi?

      • Báwo ni wọ́n ṣe ṣèrìbọmi fún Jésù? Ṣé wọ́n kàn wọ́n omi lé e lórí ni?

      Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà gbé fún un. Ka Lúùkù 3:21-23 àti Jòhánù 6:38, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, iṣẹ́ wo ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀?

      5. Má bẹ̀rù láti ṣe ìrìbọmi

      Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi lè kọ́kọ́ dẹ́rù bà ẹ́. Àmọ́ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ọkàn rẹ á túbọ̀ máa balẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí. Kó o lè rí àpẹẹrẹ àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀, Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Bá A Ṣe Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Jèhófà (1:11)

      Ka Jòhánù 17:3 àti Jémíìsì 1:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ táá fi múra tán láti ṣèrìbọmi?

      A. Obìnrin kan ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tó fẹ́ ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un. B. Obìnrin kan náà ń ṣèrìbọmi kó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ńṣe ni wọ́n rì í bọnú omi pátápátá.
      1. Tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe là ń sọ fún un pé ó wù wá láti máa sìn ín títí ayé

      2. Tá a bá ń ṣèrìbọmi, ńṣe là ń sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run

      6. Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, ó ti di ara ìdílé Jèhófà nìyẹn

      Tá a bá ti ṣèrìbọmi, a ti di ara ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, bí wọ́n sì ṣe tọ́ wa dàgbà yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà la gbà gbọ́, ìlànà ìwà rere kan náà la sì ń tẹ̀ lé. Ka Sáàmù 25:14 àti 1 Pétérù 2:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, báwo ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ṣe máa rí?

      Àwòrán: Inú arábìnrin kan tó ti ṣèrìbọmi ń dùn bó ṣe ń ronú nípa àjọṣe tó dáa tó ní pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. 1. Arábìnrin yẹn sọ ìṣòro ẹ̀ fún arábìnrin kan. 2. Ó di arábìnrin àgbàlagbà kan mú kó má bàa ṣubú bí wọ́n ṣe ń rìn lọ. 3. Òun àtàwọn ará kan nínú ìjọ ń jẹun pa pọ̀. 4. Ó ń wàásù fún ọkùnrin kan, arábìnrin kan sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 5. Ó wà ní àpéjọ agbègbè, ó ń ya fọ́tò pẹ̀lú àwọn arábìnrin méjì tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra.

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò tíì ṣe tán láti ṣèrìbọmi.”

      • Ṣó o rò pé ó yẹ kéèyàn máa fi ìrìbọmi falẹ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Jésù kọ́ wa pé ó pọn dandan káwọn tó bá fẹ́ di Kristẹni ṣèrìbọmi. Kí ẹnì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, kó máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kó sì ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí ni ìrìbọmi, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

      • Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

      • Àwọn nǹkan wo ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi.

      “Kí Ni Ìrìbọmi?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi.

      “Tó O Bá Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Tó O sì Mọyì Rẹ̀, Wàá Ṣèrìbọmi” (Ilé Ìṣọ́, March 2020)

      Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí ọkùnrin kan ní sí Ọlọ́run ló mú kó ṣèrìbọmi.

      “Wọ́n Fẹ́ Kí Èmi Fúnra Mi Wádìí Láti Mọ Ohun Tí Bíbélì Sọ” (Ilé Ìṣọ́, February 1, 2013)

      Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé ìgbésẹ̀ pàtàkì ni ìrìbọmi. Wàá tún rí bó o ṣe lè múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi.

      “Ṣó Yẹ Kí N Ṣèrìbọmi?” (Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, orí 37)

      a Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀, ńṣe la máa tún ìrìbọmi ṣe fún ẹni náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀sìn yẹn kò kọ́ni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.​—Wo Ìṣe 19:1-5 àti Ẹ̀kọ́ 13.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́