ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | February 1
    • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’

      “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa bamtisi wọn ni orukọ . . . ẹmi mímọ́.”—MATIU 28:19, NW.

      1. Ọrọ titun wo ni Johanu Arinibọmi lo ni isopọ pẹlu ẹmi mímọ́?

      NI ỌDUN 29 ti Sanmani Tiwa, Johanu Arinibọmi jẹ́ agbékánkánṣiṣẹ́ ni Isirẹli ninu pipese ọna silẹ fun Mesaya naa, ati lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, ó kéde ohun kan ti ó jẹ́ titun nipa ẹmi mímọ́. Nitootọ, awọn Juu ti mọ ohun ti Iwe Mímọ́ lede Heberu wi nipa ẹmi tẹlẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹnu ti lè yà wọn nigba ti Johanu wi pe: “Loootọ ni emi ń fi omi bamtisi yin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti . . . ń bọ lẹhin mi, . . . yoo fi ẹmi mímọ́ . . . bamtisi yin.” (Matiu 3:11) ‘Fifi ẹmi mímọ́ bamtisi’ jẹ́ ifihan titun kan.

      2. Ọrọ titun wo ni Jesu nasẹ ti ó wémọ́ ẹmi mímọ́?

      2 Ẹni naa ti ń bọ ni Jesu. Lakooko igbesi-aye rẹ̀ ori ilẹ-aye, Jesu kò fi ẹmi mímọ́ bamtisi ẹnikẹni, bi o tilẹ jẹ pe oun sọrọ nipa ẹmi naa ni ọpọlọpọ ìgbà. Ju bẹẹ lọ, lẹhin ajinde rẹ̀, ó tọka si ẹmi mímọ́ ni ọna titun miiran sibẹ. Ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa bamtisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mímọ́.” (Matiu 28:19, NW) Ọrọ naa “ni orukọ” tumọsi “ni mímọ̀dájú.” Bamtisimu inu omi ni mímọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ daju ni ó nilati yatọ sí fifi ẹmi mímọ́ bamtisi lẹẹkansii. Ó tun jẹ ifihan titun pẹlu ti o mu ẹmi mimọ lọwọ.

  • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | February 1
    • Bamtisi “ni Orukọ . . . Ẹmi Mímọ́”

      5, 6. Bawo ni fifi ẹmi mímọ́ bamtisi akọkọ ṣe ṣamọna si bamtisimu ninu omi?

      5 Ṣugbọn ki ni niti bamtisimu inu omi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ ti a ṣeleri? Awọn ọmọ-ẹhin akọkọ wọnni ti a fi ẹmi bamtisi kò niriiri iru bamtisimu inu omi kan bẹẹ. Wọn ti gba bamtisimu inu omi ti Johanu ṣaaju, niwọn ìgbà ti iyẹn sì ti ṣetẹwọgba fun Jehofa ni akoko pato yẹn, a kò nilati tún wọn bamtisi mọ́. Ṣugbọn ni Pẹntikọsi 33 C.E., ogunlọgọ nla awọn ọkàn gba bamtisimu inu omi titun naa. Bawo ni eyi ṣe wáyé?

      6 Fifi ẹmi mímọ́ bamtisi 120 ni ariwo ńlá kan ti ó fa awọn ogunlọgọ mọra ti bá rìn. Awọn wọnyi ni ẹnu yà lati gbọ ti awọn ọmọ-ẹhin ń fi èdè fọ̀, iyẹn ni pe, ní awọn èdè ajeji ti awọn ti ó wà nibẹ loye. Apọsiteli Peteru ṣalaye pe iṣẹ iyanu yii jẹ́ ẹ̀rí pe ẹmi Ọlọrun ni a ti tú jade nipasẹ Jesu, ẹni ti a ti ji dide lati inu oku ti ó sì jokoo nisinsinyi ni ọwọ ọtun Ọlọrun ni ọrun. Peteru fun awọn olugbọ rẹ̀ niṣiiri pe: “Ki gbogbo ile Isirẹli mọ̀ dajudaju pe Ọlọrun ti sọ ọ di Oluwa ati Kristi, Jesu yii ẹni ti ẹyin kànmọ́gi.” Oun lẹhin naa pari ọrọ nipa sisọ pe: “Ẹ ronupiwada, ẹ sì jẹ́ ki a bamtisi olukuluku yin ni orukọ Jesu Kristi fun idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀ yin, ẹyin yoo si rí ẹbun ọ̀fẹ́ ẹmi mímọ́ gbà.” Nǹkan bi 3,000 ọkàn dahunpada.—Iṣe 2:36, 38, 41, NW.

      7. Ni ọna wo ni 3,000 ti a bamtisi ni Pẹntikọsi 33 C.E. gbà ṣe bamtisi ni orukọ ti Baba, ti Ọmọkunrin, ati ti ẹmi mímọ́?

      7 Njẹ a lè sọ pe awọn wọnyi ni a bamtisi ni orukọ (ni mímọ) Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ (dájú) bi? Bẹẹni. Bi o tilẹ jẹ pe Peteru kò sọ fun wọn lati bamtisi ni orukọ Baba, wọn mọ Jehofa daju gẹgẹ bi Oluwa Ọba-alaṣẹ tẹlẹ, niwọn bi wọn ti jẹ Juu nipa ti ara, mẹmba orilẹ-ede kan ti a yà sí mímọ́ fun un. Peteru kò sọ pe: ‘Ẹ bamtisi ni orukọ Ọmọkunrin.’ Nitori naa bamtisimu wọn duro fun mímọ Jesu daju gẹgẹ bi Oluwa ati Kristi wọn. Wọn jẹ́ ọmọ-ẹhin rẹ̀ nisinsinyi wọn sì gba pe idariji awọn ẹṣẹ wọn jẹ́ nipasẹ rẹ̀ lati isinsinyi lọ. Nikẹhin, bamtisimu naa jẹ́ ni mímọ ẹmi mímọ́ daju, a sì ṣe é ni idahunpada si ileri naa pe wọn yoo gba ẹmi naa gẹgẹ bi ẹbun ọ̀fẹ́ kan.

      8. (a) Ni afikun si bamtisimu inu omi, bamtisimu miiran wo ni awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti gbà? (b) Awọn wo yatọ si 144,000 ni wọn gba bamtisimu inu omi ni orukọ ẹmi mímọ́?

      8 Awọn wọnni ti a fi omi bamtisi ni ọjọ Pẹntikọsi 33 C.E. ni a tun fi ẹmi bamtisi, ni jijẹ ẹni ti a fami ororo yan gẹgẹ bi ọba ati alufaa ọjọ-ọla ni Ijọba ti ọrun. Gẹgẹ bi iwe Iṣipaya ti wi, kiki 144,000 awọn wọnyi ni o wà. Nitori naa awọn wọnni ti a fi ẹmi bamtisi ti a ‘fi edidi di’ nikẹhin gẹgẹ bi ajumọ jogun Ijọba papọ jẹ́ 144,000. (Iṣipaya 7:4; 14:1) Bi o ti wu ki o ri, gbogbo awọn ọmọ-ẹhin titun—ohun yoowu ki ireti ọjọ-ọla wọn jẹ́—ni a bamtisi ninu omi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́. (Matiu 28:19, 20) Nigba naa, ki ni, bamtisimu ni orukọ ẹmi mímọ́ tumọsi fun awọn Kristẹni, yala ti “agbo kekere” tabi ti “agutan miiran”? (Luuku 12:32; Johanu 10:16) Ṣaaju ki a tó dahun iyẹn, ẹ jẹ ki a ṣakiyesi awọn igbokegbodo diẹ ti ẹmi ni sanmani Kristẹni.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́