ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Kọ́ni Ṣe Ń Ṣe Àwọn Ará Ìlú Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́—2012 | May 1
    • Àṣẹ tí Jésù pa pé kí wọ́n ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ jọ ìtọ́ni tó fún wọn pé kí wọ́n dà bí iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ayé. (Mátíù 5:13, 14) Báwo ni wọ́n ṣe jọra? Àǹfààní wo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa ṣe fún àwọn èèyàn?

  • Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Kọ́ni Ṣe Ń Ṣe Àwọn Ará Ìlú Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́—2012 | May 1
    • Kí nìdí tí Jésù tún ṣe fi àwọn Kristẹni wé ìmọ́lẹ̀? Bí òṣùpá ṣe ń gbé ìmọ́lẹ̀ tó wá látara oòrùn yọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ṣe ń gbé “ìmọ́lẹ̀” Jèhófà Ọlọ́run yọ. Wọ́n ń gbé ìmọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà yọ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn àti iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe.—1 Pétérù 2:12.

      Jésù túbọ̀ tẹnu mọ́ ìjọra tó wà láàárín kéèyàn dà bí ìmọ́lẹ̀ àti kéèyàn di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tó sọ pé: “Àwọn ènìyàn a tan fìtílà, wọn a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, a sì tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.” Kedere ni gbogbo àwọn tó bá wà nítòsí máa rí fìtílà tó ń jó tó wà lórí ọ̀pá fìtílà. Lọ́nà kan náà, kedere ló yẹ kí àwọn tó ń gbé ní àgbègbè ibi tí àwọn Kristẹni ń gbé máa rí iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ rere tí àwọn Kristẹni wọ̀nyí ń ṣe. Kí nìdí? Jésù sọ pé àwọn tó ń rí iṣẹ́ rere tí àwọn Kristẹni yìí ń ṣe máa fi ògo fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún àwọn Kristẹni náà.—Mátíù 5:14-16.

      Ojúṣe Gbogbo Wa Ni

      Nígbà tí Jésù sọ pé, “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé” àti pé “kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn,” gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pátá ló ń bá sọ̀rọ̀. Kì í ṣe àwọn èèyàn mélòó kan tó wà káàkiri nínú onírúurú ìsìn ló máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo onígbàgbọ́ ni “ìmọ́lẹ̀.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù méje, tí wọ́n ń gbé ní igba ó lè márùndínlógójì [235] ilẹ̀, gbà pé ojúṣe gbogbo àwọn lápapọ̀ ni láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn, kí wọ́n sì jíṣẹ́ tí Kristi rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fún wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́