ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | May 15
    • 12. (a) Kí ni Jésù sọ nípa ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí? (b) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn?

      12 Oore tó dára jù lọ tá a lè ṣe fáwọn èèyàn ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 43:3) Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn káwọn èèyàn bàa lè rí “iṣẹ́ àtàtà,” ìyẹn iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe fáwọn èèyàn. Iṣẹ́ rere yẹn á máa tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí “níwájú àwọn ènìyàn,” tàbí lédè mìíràn, á máa ṣe gbogbo arayé láǹfààní. (Ka Mátíù 5:14-16.) Lónìí, à ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn nípa ṣíṣe rere sáwọn aládùúgbò wa àti nípa wíwàásù ìhìn rere “ní gbogbo ayé,” ìyẹn “ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 26:13; Máàkù 13:10) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí!

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | May 15
    • 14. (a) Báwo ni fìtílà ọ̀rúndún kìíní ṣe rí? (b) Kí ló túmọ̀ sí lati má ṣe fi ìmọ́lẹ̀ wa pamọ́ sábẹ́ “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n”?

      14 Jésù sọ pé táwọn èèyàn bá tan fìtílà, wọn kì í gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀, àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n máa ń gbé e sí kó bàa lè tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Irú fìtílà tí wọ́n sábàá máa ń lò ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ àtùpa alámọ̀ tí wọ́n fi òwú àtùpà sí, òwú yìí á máa fa epo (tó sábàá máa ń jẹ́ òróró olífì) èyí táá máa mú kí iná jò. Ó fẹ́ jọ àtùpa karosíìnì tí wọ́n ń fi agolo tàbí ìgò ṣe lóde òní. Orí ọ̀pá tí wọ́n fi irin tàbí igi ṣe ni wọ́n máa ń gbé e sí, èyí á sì wá jẹ́ kó lè máa “tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé.” Àwọn èèyàn ò ní tan fìtílà yìí tán kí wọ́n wá gbé e sábẹ́ “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n,” ìyẹn irú apẹ̀rẹ̀ ńlá kan tá a fi ń ra nǹkan lọ́jà. Jésù ò fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun fi ìmọ́lẹ̀ wọn pamọ́, bí ìgbà tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n. Torí náà, a ní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, ká má ṣe gbà kí àtakò tàbí inúnibíni pa wá lẹ́nu mọ́ débi tá a ó fi fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ pamọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́