ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Fi “Ọgbọ́n Ọlọ́run” Hàn
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • 6-8. (a) Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn? (b) Kí ló fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ni Jésù ń lò?

      6 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fún wa nínú Mátíù orí kẹfà, nípa bá ò ṣe ní máa ṣàníyàn nípa nǹkan ìní tara. Jésù sọ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.” (Ẹsẹ 25) Gbogbo wa la nílò oúnjẹ àti aṣọ, torí náà, kò sí béèyàn ò ṣe ní máa ronú nípa bó ṣe máa ní wọn. Àmọ́ Jésù sọ pé ká “yéé ṣàníyàn” nípa àwọn nǹkan yẹn.b Kí nìdí?

      7 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn. Ó sọ pé Jèhófà ló jẹ́ ká wà láàyè, tó sì dá ara wa, torí náà, ó dájú pé ó máa pèsè oúnjẹ fún wa láti gbé ẹ̀mí wa ró, á sì pèsè aṣọ tá a máa wọ̀. (Ẹsẹ 25) Tí Ọlọ́run bá lè pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ, tó sì ṣe àwọn òdòdó lọ́ṣọ̀ọ́, ó dájú pé ó máa bójú tó àwa èèyàn tá à ń sìn ín! (Ẹsẹ 26, 28-30) Ká sòótọ́, tá a bá ń ṣàníyàn, kò lè ṣe wá láǹfààní kankan. Kódà, kò lè fi bín-ín-tín kún ìwàláàyè wa.c (Ẹsẹ 27) Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe àníyàn? Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ torí ó dájú pé gbogbo ohun tá a nílò lójoojúmọ́ ni Baba wa ọ̀run “máa fi kún un” fún wa. (Ẹsẹ 33) Jésù wá fi ìmọ̀ràn kan tó wúlò gan-an parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní ká má da àníyàn tọ̀la pọ̀ mọ́ tòní. (Ẹsẹ 34) Nígbà míì, àwọn ohun tá à ń ṣàníyàn nípa ẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀ rárá, kí wá nìdí tí àá fi máa da ara wa láàmú? Tá a bá fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fún wa yìí sílò, a ò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá ara wa bíi tọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, àá sì máa láyọ̀.

  • Jésù Fi “Ọgbọ́n Ọlọ́run” Hàn
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • b Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì tá a tú sí “ṣàníyàn” túmọ̀ sí “kí ọkàn èèyàn má pa pọ̀.” Bí wọ́n ṣe lò ó nínú Mátíù 6:25, ó túmọ̀ sí kí nǹkan máa ba èèyàn lẹ́rù, kí ọkàn ẹ̀ má sì balẹ̀ débi pé nǹkan yẹn lá máa rò ṣáá, tíyẹn ò sì jẹ́ kó láyọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́