-
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njúIlé Ìṣọ́—2003 | September 1
-
-
7, 8. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀ pé ẹ̀dá aláìpé máa ń ṣe àníyàn àṣejù nípa àwọn nǹkan tara? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni Jésù fúnni nípa bá a ṣe lè yẹra fún àníyàn tí kò yẹ?
7 Nínú Ìwàásù tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó fúnni nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.”b (Mátíù 6:25) Jésù mọ̀ pé ohun tó sábàá máa ń jẹ àwọn ẹ̀dá aláìpé lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa rí àwọn ohun kòṣeémáàní. Nígbà náà, báwo la ṣe lè “dẹ́kun ṣíṣàníyàn” nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí? Jésù sọ pé “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” Ìṣòro èyíkéyìí tó wù ká kojú, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní fífi ìjọsìn Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tá a nílò lójoojúmọ́ ni Baba wa ọ̀run á “fi kún un” fún wa. Lọ́nà kan ṣáá, ó máa pèsè ohun tá a nílò fún wa.—Mátíù 6:33.
-
-
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njúIlé Ìṣọ́—2003 | September 1
-
-
b Wọ́n sọ pé àníyàn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín jẹ́ “ìbẹ̀rù tó ń kó jìnnìjìnnì báni, tí kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀ nígbèésí ayé.” Irú àwọn ìtumọ̀ bí “Ẹ má máa ṣe àníyàn,” tàbí “Ẹ maṣe ṣe aniyan,” fi hàn pé a ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàníyàn rárá. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà fi ohun tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ hàn, tó túmọ̀ sí pé ká dá ohun tá a ń ṣe lọ́wọ́ dúró.”
-