ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 32
  • Ẹ̀kọ́ Láti Ara Àwọn Ẹyẹ àti Àwọn Òdòdó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Láti Ara Àwọn Ẹyẹ àti Àwọn Òdòdó
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 32

Ẹ̀kọ́ Láti Ara Àwọn Ẹyẹ àti Àwọn Òdòdó

KÍ NÍ sábà máa ń kan àwọn ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n ju ohunkóhun mìíràn lọ lónìí? Fún àwọn tí ó pọ̀ jùlọ, ó jẹ́ níní tó láti pèsè fún ìdílé wọn tàbí ṣíṣeéṣe láti mú ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i.

Láti lè mú kí awọ kájú ìlù jẹ́ àníyàn pàtàkì bákan náà, nígbà tí Jesu Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ pé ohun tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n yìí lè di àníyàn bíbonimọ́lẹ̀, tí yóò di àwọn ohun tẹ̀mí lójú. Láti ṣàkàwé kókó yìí, Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wo àwọn ẹyẹ àti àwọn òdòdó fínnífínní.

Àwọn ẹyẹ ní láti jẹun lójoojúmọ́—ní ìwọ̀n púpọ̀púpọ̀ ju tiwa lọ nítorí pé oúnjẹ máa ń tètè dà lára wọn. Ní àfikún sí i, wọn kò lè fún irúgbìn, ká irúgbìn, tàbí tọ́jú oúnjẹ pamọ́ fún ọjọ́ iwájú. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣàkíyèsí, “Baba” wa “ọ̀run ń bọ́ wọn.” (Matteu 6:26) Lọ́nà kan náà, Ọlọrun fi asọ ọ̀ṣọ́ ẹ̀yẹ dídára jùlọ wọ àwọn “òdòdó lílì pápá” tí ó rẹwà.—Matteu 6:28-30.

Jesu fi dá wa lójú pé bí a bá ní ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn àìní ti ara, tí a sì fi àwọn ohun tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, Ọlọrun yóò rí sí i pé a ní oúnjẹ àti aṣọ tí ó pọndandan. Bí Jehofa Ọlọrun bá ń bìkítà fún àwọn ẹyẹ àti àwọn òdòdó, dájúdájú yóò bìkítà fún àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ‘ń bá a nìṣó ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.’ (Matteu 6:33) O ha ń fi ire Ìjọba Ọlọrun sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́