-
Ìwé Àkàkọ́gbọ́n Tí Ìmọ̀ràn Rẹ̀ Wúlò Lóde ÌwòyíIlé Ìṣọ́—1999 | April 1
-
-
Nígbà tí Mihoko rí àwọn ìyípadà tí ọkọ rẹ̀ ṣe, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tó ń kọ́ sílò. Ìlànà kan tó ṣèrànwọ́ gan-an nìyí: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́.”e Nítorí náà, Mihoko àti ọkọ rẹ̀ pinnu pé àwọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ibi táwọn ti ń ṣe dáadáa, àti bí àwọn ṣe lè ṣàtúnṣe ní àwọn ibi yòókù, dípò kí àwọn máa di ẹ̀bi ru ẹnì kìíní kejì. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Mihoko rántí pé: “Ó fún mi láyọ̀ ní ti gidi. A ti ń ṣe èyí nídìí oúnjẹ ní alaalẹ́. Kódà, ọmọkùnrin wa ọlọ́dún mẹ́ta máa ń dá sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà. Ó tù wá lára gan-an!”
-