ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Wọ́n Ṣe Tán Láti Wàásù Láìka Àtakò Sí
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa kojú àtakò tó le gan-an, àmọ́ Jésù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn; torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.” Jésù tún sọ pé: “Arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n. Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi, ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.”—Mátíù 10:19-22.

  • Wọ́n Ṣe Tán Láti Wàásù Láìka Àtakò Sí
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ẹ ò rí i pé àwọn ìtọ́ni, ìkìlọ̀ àti ìṣírí tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá (12) bọ́ sákòókò gan-an! Àmọ́, àwọn nìkan kọ́ làwọn ìtọ́ni yẹn kàn, ó tún kan àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn tí Jésù bá kú tó sì jíǹde. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ pé “gbogbo èèyàn . . . máa kórìíra yín.” Lédè míì, kì í ṣe àwọn tí wọ́n wàásù fún nígbà yẹn nìkan ló máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bákan náà, Bíbélì ò sọ fún wa pé àwọn èèyàn fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sọ́dọ̀ gómìnà tàbí lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba láàárín ìwọ̀nba àkókò tí wọ́n fi wàásù ní Gálílì, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn pa èyíkéyìí lára wọn.

      Ó ṣe kedere pé nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọn ò ní lè lọ yí ká gbogbo ìlú tí wọ́n ti máa wàásù “títí Ọmọ èèyàn fi máa dé,” ohun tó ń sọ ni pé wọn ò tíì ní parí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run títí Jésù Kristi ọba fi máa wá ṣe ìdájọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́