ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Mọ Iye ‘Irun Orí Rẹ’
    Ilé Ìṣọ́—2005 | August 1
    • 6 Káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lè rí ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n bẹ̀rù, Jésù sọ àkàwé méjì fún wọn. Ó ní: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Kíyè sí i pé, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà bìkítà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kò ní jẹ́ ká bẹ̀rù nígbà tá a bá ń dójú kọ àtakò. Kò sí àní-àní pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa? Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?” (Róòmù 8:31, 32) Irú ìṣòro tó wù kí ìwọ náà ní, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà bìkítà fún ọ níwọ̀n ìgbà tó o bá ti jẹ́ olóòótọ́ sí i. Wàá túbọ̀ rí i pé òótọ́ ló bìkítà fún ọ bá a ti ń ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀.

      Iye Owó Ológoṣẹ́

      7, 8. (a) Irú ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo ẹyẹ ológoṣẹ́ nígbà ayé Jésù? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ológoṣẹ́ wẹ́wẹ́” ni wọ́n dìídì lò nínú Mátíù 10:29?

      7 Àwọn àpèjúwe tí Jésù lò jẹ́ ká rí i pé Jèhófà bìkítà fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ yẹ̀ wò ná. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn máa ń jẹ ẹyẹ ológoṣẹ́, àmọ́ nítorí pé wọ́n máa ń ba irè oko jẹ́, ọ̀tá àgbẹ̀ ni wọ́n kà wọ́n sí. Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí pọ̀ gan-an nígbà yẹn, iye tí wọ́n sì ń tà wọ́n kéré débi pé, tá a bá ṣírò rẹ̀ lówó òde òní, iye téèyàn á fi ra méjì kò tó náírà mẹ́fà. Téèyàn bá wá ní ìlọ́po méjì owó yẹn lọ́wọ́, ológoṣẹ́ márùn-ún ni wọ́n máa kó fún un kì í ṣe mẹ́rin. Èènì ni wọ́n fi ọ̀kan tó lé lórí rẹ̀ yẹn ṣe, bíi pé ẹyọ kan yẹn kò níye lórí rárá!—Lúùkù 12:6.

      8 Tún ronú lórí bí ẹyẹ tó wọ́pọ̀ gan-an yìí ṣe kéré tó. Tá a bá fi ológoṣẹ́ wé àwọn ẹyẹ mìíràn, ológoṣẹ́ tó tiẹ̀ ti dàgbà dáadáa pàápàá kéré gan-an. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ológoṣẹ́” nínú Mátíù 10:29 dìídì tọ́ka sí ológoṣẹ́ wẹ́wẹ́. Kò sí àní-àní pé ìdí tí Jésù fi fi ológoṣẹ́ ṣàpèjúwe ni pé ó fẹ́ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ronú nípa ẹyẹ kan tí kò tiẹ̀ níye lórí rárá.

      9. Kókó tó ṣe pàtàkì gan-an wo ni àkàwé Jésù nípa àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ gbé yọ?

      9 Bí Jésù ṣe lo ẹyẹ ológoṣẹ́ láti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé kókó kan tó ṣe pàtàkì gan-an yọ. Kókó náà ni pé, ohun tó lè dà bíi pé kò jẹ́ nǹkan kan lójú ẹ̀dá èèyàn ṣe pàtàkì gan-an lójú Jèhófà Ọlọ́run. Jésù túbọ̀ gbé kókó yìí yọ nígbà tó sọ pé, ẹyẹ ológoṣẹ́ tó kéré gan-an kò lè “jábọ́ lulẹ̀” kí Jèhófà má mọ̀.c Ẹ̀kọ́ tó fẹ́ ká kọ́ níbẹ̀ ṣe kedere. Bí Jèhófà Ọlọ́run bá ń kíyè sí ẹyẹ tó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹyẹ, èyí tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó dájú pé yóò kíyè sí ìṣòro àwọn ẹ̀dá èèyàn tó pinnu láti sìn ín!

  • Jèhófà Mọ Iye ‘Irun Orí Rẹ’
    Ilé Ìṣọ́—2005 | August 1
    • c Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun tí àpèjúwe náà dá lé lórí tiẹ̀ lè nítumọ̀ mìíràn tó ju pé ẹyẹ ológoṣẹ́ náà kú nígbà tó jábọ́ lulẹ̀. Wọ́n ni ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ẹyẹ náà ṣe máa ń fò wálẹ̀ láti jẹun ni ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò fún gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé Ọlọ́run ń kíyè sí ẹyẹ yìí ó sì ń bójú tó o lójoojúmọ́, kì í ṣe pé ó ń mọ̀ nígbà tó bá kú nìkan.—Mátíù 6:26.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́