ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • 18-20. (a) Kí nìdí tí Jésù fi lo agbára rẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o ronú nípa ọ̀nà tí Jésù gbà tọ́jú ọkùnrin kan tó nílò ìtọ́jú tó ṣàrà ọ̀tọ̀?

      18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù lágbára gan-an, ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn alákòóso ayé yìí tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa ń lo agbára bó ṣe wù wọ́n láìka ti ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn sí. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lógún ní tiẹ̀. Ó máa ń dùn ún gan-an tó bá rí i táwọn èèyàn ń jìyà, ó sì máa ń rí i pé òun wá nǹkan ṣe láti yanjú ìṣòro wọn. (Mátíù 14:14) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ó tún máa ń fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ̀ wò, ìyẹn sì máa ń mú kó lo agbára rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan tó wúni lórí wà nínú Máàkù 7:31-37.

      19 Lọ́jọ́ kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbé àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì wo gbogbo wọn sàn. (Mátíù 15:29, 30) Àmọ́, Jésù kíyè sí ọkùnrin kan láàárín wọn, tó nílò ìtọ́jú tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọkùnrin náà ò gbọ́ràn, kò sì lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti kíyè sí i pé ẹ̀rù ń ba ọkùnrin náà tàbí pé ojú ń tì í. Torí náà, Jésù gba tiẹ̀ rò, ó sì mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò yẹn. Jésù wá ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ ohun tóun fẹ́ ṣe fún un. Ó “ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.”c (Máàkù 7:33) Lẹ́yìn náà, Jésù wo ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀. Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yẹn máa jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé agbára Ọlọ́run ló fẹ́ fi wo òun sàn. Jésù wá sọ pé: “Là.” (Máàkù 7:34) Bó ṣe di pé ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́rọ̀ nìyẹn, tó sì lè sọ̀rọ̀ ketekete.

  • “Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • c Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ló gbà pé itọ́ wà lára ohun tí wọ́n lè fi woni sàn. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Jésù tutọ́ kó lè jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé òun fẹ́ wò ó sàn. Èyí ó wù kó jẹ́, ó dájú pé itọ́ kọ́ ni Jésù fi wo ọkùnrin náà sàn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́