ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìran Ìyípadà Ológo
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Kesaríà ti Fílípì tó wà ní nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí Òkè Hámónì, ó sọ ohun kan tó ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́nu, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.”—Mátíù 16:28.

      Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà ò ní yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dáadáa. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ìyẹn Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù lọ sórí òkè kan tó ga gan-an. Ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ti ṣú nígbà yẹn torí pé oorun ti ń kun àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bí Jésù ṣe ń gbàdúrà, Ọlọ́run yí i pa dà níṣojú wọn. Àwọn àpọ́sítélì rí ojú ẹ̀ tó tàn yòò bí oòrùn, aṣọ ẹ̀ di funfun báláú, ó sì ń tàn yinrin.

  • Ìran Ìyípadà Ológo
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ẹ wo bí ìran yẹn ṣe máa fún Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lókun! Ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn rí bí ògo Jésù ṣe máa pọ̀ tó nínú Ìjọba rẹ̀. Wọ́n rí “Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀” bí Jésù ṣe ṣèlérí fún wọn tẹ́lẹ̀. (Mátíù 16:28) Nígbà tí wọ́n wà lórí òkè yẹn, wọ́n “fi ojú ara [wọn] rí ọlá ńlá rẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí fẹ́ kí Jésù fún àwọn ní àmì kó lè dá wọn lójú pé ọba tí Ọlọ́run yàn ni, kò fún wọn lámì kankan. Àmọ́, Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó sún mọ́ ọn rí ìran ìyípadà ológo náà, ìyẹn sì mú kó dá wọn lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run máa ṣẹ. Ìyẹn ló mú kí Pétérù sọ nígbà tó yá pé: “A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú.”—2 Pétérù 1:16-19.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́