ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Kristian Obìnrin yẹ fún Ọlá àti Ọ̀wọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | July 15
    • 10 Nípa ìkọ̀sílẹ̀, a bi Jesu ní ìbéèrè yìí pé: “Ó ha bófinmu fún ọkùnrin lati kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?” Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Marku, Jesu sọ pé: “Ẹni yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ [bíkòṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè] tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i, bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹlu òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.” (Marku 10:10-12; Matteu 19:3, 9) Àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ wẹ́rẹ́ wọ̀nyẹn fi ọ̀wọ̀ hàn fún iyì àwọn obìnrin. Báwo ni ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

  • Àwọn Kristian Obìnrin yẹ fún Ọlá àti Ọ̀wọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | July 15
    • 12. Nípa ọ̀rọ̀ náà “ṣe panṣágà lòdì sí i,” ìpilẹ̀ èrò wo ni Jesu ń nasẹ̀ rẹ̀?

      12 Èkejì ni pé, nípa ìsọjáde náà “ṣe panṣágà lòdì sí i,” Jesu nasẹ̀ ojú-ìwòye kan tí ilé-ẹjọ́ rabi kò tẹ́wọ́gbà—ìpìlẹ̀-èrò náà pé ọkọ kan ṣe panṣágà lòdì sí aya rẹ̀. Ìwé The Expositor’s Bible Commentary ṣàlàyé pé: “Nínú ìsìn àwọn Júù ti rabi obìnrin kan nípa àìṣòótọ́ lè ṣe panṣágà lòdì sí ọkọ rẹ̀; ọkùnrin kan sì lè, ṣe panṣágà lòdì sí ọkùnrin mìíràn, nípa níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan kò lè ṣe panṣágà lòdì sí ìyàwó rẹ̀, ohun yòówù kí ó ṣe. Nípa fífi ọkùnrin sábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe kan náà pẹ̀lú obìnrin níti ìwàhíhù, Jesu gbé ipò àti iyì àwọn obìnrin ga.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́