ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Tọ̀ Ọ́ Wá”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • 2 Lẹ́yìn ìjíròrò tó rinlẹ̀ tí Jésù ní pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn kan, ohun kékeré kan dí i lọ́wọ́. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọ wọn wá wò ó. Ó ṣe kedere pé ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà yàtọ̀ síra, torí ọ̀rọ̀ tí Máàkù fi júwe ọmọ ọdún méjìlá kan báyìí ló fi júwe wọn, àmọ́ Lúùkù ní tiẹ̀ lo ọ̀rọ̀ tó ṣeé tú sí “ìkókó.” (Lúùkù 18:15; Máàkù 5:41, 42; 10:13) Kò kúkú síbi táwọn ọmọdé bá wà tí wọn ò ní máa ṣeréepá tàbí kí wọ́n máa pariwo kí ibẹ̀ sì máa hó yèè. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wá bá àwọn òbí àwọn ọmọ náà wí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí tí wọ́n rò pé ọwọ́ Ọ̀gá àwọn ti dí ju pe káwọn ọmọ kan tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa dààmù rẹ̀ lọ. Kí ni Jésù wá ṣe?

  • “Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Tọ̀ Ọ́ Wá”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • 4, 5. (a) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni Jésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?

      4 Bí Jésù bá jẹ́ òṣónú tàbí agbéraga, bóyá làwọn ọmọdé yẹn ì bá fẹ́ láti sún mọ́ ọn; ì bá sì má rọrùn fáwọn òbí wọn láti sún mọ́ ọn. Bó o ṣe ń fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ṣé o ò máa rí i pé ṣe ni inú àwọn òbí yẹn á máa dùn ṣìnkìn bí ọ̀gbẹ́ni tí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn yìí ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn ṣeré, tó sì ń fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọdé àti pé ó kà wọ́n sì pàtàkì? Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá tó tóbi jù lọ ló wà lọ́rùn Jésù nígbà yẹn, síbẹ̀, òun ni ẹni tó ṣeé sún mọ́ jù lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́