Irapada Ẹkọ-Igbagbọ Kristẹndọm Tí Ó Ti Sọnù
IRAPADA, igbagbọ naa pe Jesu ku ni paṣipaarọ fun araye ẹlẹṣẹ, ṣe pataki julọ fun isin Kristian tootọ. Sibẹ, ẹkọ-igbagbọ naa ti wa tipẹtipẹ labẹ ìpẹ̀gàn ati ariwisi lọdọ awọn ẹlẹkọọ-isin Kristẹndọm.
Eeṣe ti iyẹn fi ri bẹẹ? Njẹ Jesu funraarẹ ko ha sọ ni Maaku 10:45 pe: “Nitori Ọmọ eniyan tikalaarẹ ko ti wa ki a ba maa ṣe iranṣẹ fun, bikoṣe lati maa ṣe iranṣe funni, ati lati fi ẹmi rẹ ṣe irapada fun ọpọlọpọ eniyan”?
Awọn kan ti jẹwọsọ pe Jesu ko sọ awọn ọrọ wọnyi rara, pe lẹhin iku rẹ ni a hùmọ̀ wọn labẹ agbara idari apọsteli Pọọlu. Awọn miiran jiyan pe “irapada” nihin-in jẹ apejuwe ọrọ tabi pe ẹkọ-igbagbọ naa wá lati inu itan arosọ Giriiki! Nitori naa irapada ti fẹrẹẹ poora ninu awọn ẹkọ ṣọọṣi.
Ṣugbọn, iwọ le ṣe kayefi pẹlu, bi awọn Kristian ijimiji ṣe loye iku Jesu. Pọọlu sọ fun wa ni 2 Kọrinti 5:14, 15 pe: “Nitori ifẹ Kristi nrọ wa; nitori awa ro bayii, pe bi ẹnikan ba ti ku fun gbogbo eniyan . . . ki awọn ti o walaaye ki o ma si ṣe walaaye fun ara wọn mọ bikoṣe fun ẹni ti o ku nitori wọn, ti o si ti jinde.” Ẹ wo bi ẹkọ-igbagbọ yii ti rọrun to lọna ti o kun fun itumọ—ti ó wà lominira patapata kuro lọwọ awọn ìtọwọ́bọ̀ didiju ti a o wa ṣe lati ọwọ awọn ẹlẹkọọ-isin ṣọọsi nikẹhin.
O ha ṣeeṣe pe ki Pọọlu hùmọ̀ ẹkọ-igbagbọ yii? Bẹẹkọ, nitori oun ṣalaye ni 1 Kọrinti 15:3 pe: “Nitori pe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyi ti emi pẹlu ti gba le yin lọwọ, bi Kristi ti ku fun ẹṣẹ wa gẹgẹbi Iwe Mimọ ti wi.” Ni kedere, tipẹ ṣaaju ki Pọọlu to kọ awọn iwe rẹ, awọn Kristian ti loye iku Jesu si ẹbọ, iye-owo gidi kan ti a san lati tun araye ẹlẹṣẹ rà pada, irapada kan. Siwaju sii pẹlu, gẹgẹbi Pọọlu ti fihan, wọn loye pe iku Kristi mu “Iwe mimọ” ṣẹ, iyẹn ni, awọn asọtẹlẹ bii Saamu 22 ati Aisaya 53 ninu Iwe Mimọ lede Heberu, tabi “Majẹmu Laelae.”
Awọn Ibeere Ti A Ko Dahun
Bi iwọ ba yan lati ṣewadii awọn otitọ naa fun araarẹ, iwọ yoo rii pe awọn ẹkọ ipẹhinda yọ́ wọnu isin Kristian pada sẹhin sunmọ akoko awọn apọsteli. (Iṣe 20:29, 30; 2 Timoti 4:3, 4) Sibẹ, igbagbọ ninu ẹbọ irapada Kristi nbaa lọ, gẹgẹbi ikọwe awọn Baba Ṣọọṣi ijimiji ti fihan. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti awọn ẹlẹkọọ-isin kan lẹhin naa walẹjin lọ sinu ẹkọ-igbagbọ irapada, wọn jade wa pẹlu awọn ibeere ṣiṣoro kan, iru bii, Ta ni a san irapda naa fun? Eesitiṣe ti iru sisan bẹẹ fi pọndandan?
Ni ọrundun kẹrin C.E., Gregory ti Nyssa ati awọn miiran làdí oju-iwoye naa pe irapada ni a ti san fun Satani Eṣu! Wọn jiyan pe, Satani ní eniyan níkàáwọ́, ati pe irapada ni a san fun un lati tu araye silẹ. Bi o ti wu ki o ri, alajọgbaye rẹ kan ti a npe ni Gregory ti Nazianzus ri alafo fẹ̀ǹfẹ̀ kan ninu àbá ero-ori yii: o dọgbọn tumọsi pe Ọlọrun jẹ Eṣu ni gbese—eyi ti ko bọgbọnmu nitootọ! Bi o tilẹ ri bẹẹ, ero naa pe irapada ni a san fun Eṣu di mímọ̀ o si wà pẹtiti fun ọpọ ọrundun.
Njẹ irapada naa ni a ti le san fun Ọlọrun funraarẹ bi? Gregory ti Nazianzus nimọlara pe oun tun ri awọn iṣoro pẹlu ero yii. Niwọnbi ‘awa ko ti wa ninu ide isinru lọdọ Ọlọrun,’ eeṣe ti a fi nilo lati san irapada kan fun un? Siwaju sii pẹlu, ‘Baba ha le nínúdídùn ninu iku Ọmọkunrin rẹ bi’ nipa fifi dandangbọn beere irapada kan? Awọn ibeere ti wọn jọ bi eyi ti o ṣoro ni o dabi ẹnipe wọn fi irapada naa fúnraarẹ̀ sabẹ iyemeji.
Iku Irapada Naa
Iwadii rẹ lori koko-ọran yi le mu ọ de ibẹrẹ ọrundun kejila. Anselm, Olori biṣọọbu ti Canterbury, gbiyanju lati dahun awọn ibeere wọnyi ninu iwe rẹ Cur Deus Homo (Idi ti Ọlọrun Fi Di Eniyan). Iwe naa kọni pe iku Kristi ṣiṣẹ gẹgẹbi ọna naa fun títẹ́ idajọ ododo atọrunwa lọrun, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe gẹgẹbi irapada kan. Anselm gbàgbọ́ pe lati dari ẹṣẹ jì nipasẹ irapada kan láìtẹ́ idajọ-ododo lọrun yoo tumọsi lati fi ẹṣẹ silẹ laiṣatunṣe. “Ṣugbọn Ọlọrun ko lee fi ohunkohun silẹ lọna titọ laiṣatunṣe ninu Ijọba Rẹ” ni Anselm wi. Nigba naa, bawo ni Ọlọrun ṣe ṣatunṣe awọn ọran?
Ni jijiyan pe ‘ẹṣẹ ntabuku si Ọlọrun,’ Anselm wipe kì bá má ti tó “lati mu ohun ti a ti gba lọ” nipasẹ ẹṣẹ Adamu “padabọsipo ni ṣakala.” Niwọnbi a ti fìwọ̀sí lọ Ọlọrun, irapada kan—ani ẹbọ ẹda-eniyan pipe paapaa—ko ni tó. Alufaa ojiṣẹ naa ronu pe, “Bi a ba gba ìwọ̀sí ti a filọ ọ yẹwo, ohun ti a san pada gbọdọ ju ohun ti a gba lọ.” [ikọwe winniwinni jẹ tiwa.] Anselm jiyan pe eyi beere fun iku ẹnikan ti o jẹ “Ọlọrun ati eniyan papọ”!
Ohunyoowu ti ihuwapada rẹ si awọn ẹkọ Anselm le jẹ, wọn bori ti awọn alajọgbaye rẹ wọn si nbaa lọ lati lo agbara idari ni ọjọ wa. Họọwu, lẹẹkanṣoṣo fáú, Anselm ti fun ẹkọ-igbagbọ Mẹtalokan lokun o si ti ko ajalu iku ba irapada naa, o kere tan ninu Kristẹndọm! “Itẹlọrun” wa di ohun ti awọn ẹlẹkọ-isin fi nṣe ọrọ sọ, ede isọrọ naa “irapada” npoora diẹdiẹ wọnu okunkun bàìbàì. Laika eyiini si, awọn àbá ero-ori Anselm ni o fẹrẹẹ jẹ pe a gbe gbogbo rẹ̀ kari ọgbọn ironu adamọdi, kii ṣe lori Bibeli. Bi akoko si ti nkọja, awọn ọmọwe akẹkọọ jinlẹ iru bii Thomas Aquinas bẹrẹsii yìnrìn aba ero-ori Anselm nipa “itẹlọrun” dànù pẹlu ọgbọn ironu jijafafa tiwọn fúnraawọn. Ìméfò wa di pupọ. Awọn àbá ero-ori itunrapada pọ sii, ariyanjiyan naa si nsun siwaju jinna si Iwe Mimọ ati jinlẹjinlẹ sinu ironu, ọgbọn imọ ọran, ati imọ iṣẹ́ awo ẹda-eniyan.
Atunṣebọsọna ati Irapada Naa
Laika eyi si, ẹ jẹ ki a sunmọ akoko wa timọtimọ diẹ sii. Nigba ti ìjì Atunṣebọsọna Protestant ru dide ni ọrundun kẹrindinlogun, awujọ oniyiipada tegbotigaga kan ti a npe ni awọn ọmọlẹhin Socinus ni a bi.a Wọn sẹ́ pe iku Jesu ni ọnakọna “mu wa lẹtọọ si igbala,” ni pipe iru igbagbọ bẹẹ ni “aṣinilọna, akun fun aṣiṣe, ati apanilara gan-an . . . , ti o lodi si Iwe Mimọ ati iwoyeronu.” (The Racovian Catechisme) Niwọnbi Ọlọrun ti ndariji lọfẹẹ, itẹlọrun idajọ-ododo eyikeyii ni ko pọndandan. Wọn sọ pẹlu idaniloju pe iku Jesu tunnirapada niti pe o sun awọn eniyan lati ṣe afarawe apẹẹrẹ rẹ.
Ṣọọṣi Katoliki, ti a kọlu nipasẹ iwọnyi ati awọn adamọ miiran, ṣe ifilọlẹ igbejako pada kan, ni pipe apejọ Ajọ-igbimọ Trent (Lati 1545 si 1563 C.E.). Ṣugbọn nigba ti a mu iduro kan pato lori ọpọlọpọ awọn ariyanjiyan ẹkọ-igbagbọ, apero naa ko ṣe kedere ko si sọ ero kan pato nipa itunrapada. O sọrọ nipa ‘itoye Jesu Kristi’ o si lo ede-isọrọ naa “itẹlọrun” ṣugbọn o fi tiṣọratiṣọra yẹra fun ede-isọrọ naa “irapada” Ni àbárèbábọ̀, ṣọọṣi naa jinna si nini ero kan pato ti o ṣekedere ti o si ba Iwe Mimọ mu. Ilẹkun imefo wà ni ṣiṣisilẹ gbagada sibẹ.
Idi Ti awọn Aṣaaju Isin Fi Kuna
Lati igba Ajọ-igbimọ Trent, awọn ẹlẹkọ-isin—Katoliki ati Protestant bakan naa—ti mu aba ero-ori itunrapada ti kò niye jade. (Wo apoti ni oju-iwe 7.) Sibẹ, ko si ifohunṣọkan lori itumọ iku Jesu ni ojutaye. Awọn ẹlẹkọọ-isin fohunṣọkan lori kiki ṣiṣai ka ede isọrọ ti Iwe Mimọ naa “irapada” si pataki, ni yiyan lati ṣaa ti ki wọn fi wọlẹ tabi ṣalaye rẹ lọna ti ko fi ni jootọ. Itumọ iku Kristi ni a ṣalaye rẹ pẹlu ẹnà ọ̀rọ̀ ẹlẹ́lọ̀ọ́, ọgbọn ironu aṣinilọna ti o lójúpọ̀ ti o si takókó, ati awọn ede-isọrọ alainitumọ, iru bi “agbara idari lori iwarere” ati “aṣoju itẹlọrun ti ara.” Dipo gbigbe igbagbọ ró ninu iku Kristi, awujọ alufa Kristẹndọm ti sọ opo-igi idaloro rẹ̀ di okuta idigbolu ti ńṣinilọ́nà.
Ki ni idi ti o wa labẹ ikuna buruku yii? Ẹlẹkọọ-isin Katoliki naa Boniface A. Willems ka a si otitọ pe awọn ẹlẹkọọ-isin ni a “kọlẹkọọ ni ìdákọ́ńkọ́ ti a pamọ daradara”—ti o ti jinna jù si aini gidi ti awọn eniyan.b Njẹ iwọ ko ha ni ìtẹ̀sí lati fohunṣokan pẹlu èrò yẹn? Bi o ti wu ki o ri, Jeremaya 8:9 tẹsiwaju, ni titọkasi gbongbo iṣoro naa gan-an: “Saa wo o, wọn ti kọ ọrọ Oluwa [“Jehofa,” NW]! Ọgbọn wo ni o wa ninu wọn?”
Ki a gba pe, ẹkọ-igbagbọ irapada le gbe awọn ibeere lilekoko melookan dide. (2 Peteru 3:16) Ṣugbọn dipo wiwa inu Iwe Mimọ fun idahun, awọn ẹlẹkọ-isin ti lo ijinlẹ oye ati ọgbọn ironu eniyan. (1 Kọrinti 1:19, 20; 2:13) Wọn ti kùgbùù lati kọ̀ awọn apa Bibeli eyikeyii ti ko ba awọn ero—tabi àbá ero-ori wọn mu silẹ. (2 Timoti 3:16) Wọn ti ṣagbatẹru awọn ẹkọ ti ko ba iwe mimọ mu, iru bii ẹkọ-igbagbọ Mẹtalọkan. (Johanu 14:28) Ikuna titobijulọ wọn si ni pe wọn ti sọ igbala eniyan di pataki julọ, ni ṣiṣa ariyanjiyan ti o wuwo ju ti o mú orukọ ati Ijọba Ọlọrun lọwọ tì.—Matiu 6:9, 10.
Alagbawi Irapada Naa
Jọwọ, nisinsinyi gbe iṣayẹwo rẹ lọ si opin awọn ọdun 1800. Ọkunrin olubẹru Ọlọrun kan ti orukọ rẹ̀ njẹ Charles Taze Russell ya ara rẹ sọtọ kuro laaarin ẹkọ-igbagbọ ti o wa lode o si bẹrẹsii tẹ iwe irohin yii gan-an—The Watch Tower (Ile-iṣọ Na) jade. Russell sọyeranti pe, “lati ibẹrẹ, o ti jẹ agbẹnusọ akanṣe fun Irapada naa.”
Ilé-ìṣọ́nà nbaa lọ lati ṣe bẹẹ titi di oni yi. Fun nkan ti o ti ju ọgọrun ọdun lọ, o ti gbe awọn idi yiyekooro ti o ba iwe mimọ mu kalẹ lati gbagbọ ninu irapada naa, o si ti funni ni awọn idahun ti o lọgbọn ninu ti o si ba Iwe Mimọ mu fun ipenija alariiwisi. Nitori naa awa ke si ọ lati wadii ohun ti Bibeli wi siwaju sii nipa iku Jesu ati itumọ rẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Awọn Socinus—Eeṣe Ti Wọn Fi Ṣa Mẹtalọkan Ti?” ninu iwe irohin wa keji Ji! ti May 22, 1989.
b Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi aba ero-ori Willems funraarẹ ninu apoti ti o wa loke.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
ṢISAYẸWO AWỌN ÀBÁ-ÈRÒ-ORI ITUNRAPADA
◻ ÀBÁ ERO ORI ALUFAA, TABI IJỌBA: Ẹlẹkọọ-isin ara Dutch Hugo Grotius mu eyi jade ni ọrundun kẹtadinlogun lati já àbá ero-ori awọn onisin Socinus nírọ́. Grotius wo iku Kristi “gẹgẹbi iru ìdúnàádúrà ti ofin kan nibi ti Ọlọrun ti wa nipo Alufaa tabi Gomina ti eniyan wa nipo ẹlẹṣẹ.”—Hastings’ Encyclopædia of Religion and Ethics.
◻ ÀBÁ ERO ORI IJẸPATAKI ÈTÙTÙ: Eyi ni a dabaa ni 1946 lati ọwọ ẹlẹkọọ-isin Protestant Clarence H. Hewitt. Oun wo iṣẹ Kristi kii ṣe gẹgẹbi ijiya idajọ ofin kan, ṣugbọn gẹgẹbi eyi ti ‘ntu wa silẹ kuro ninu ijẹgaba lenilori ti ofin ẹṣẹ ati iku ti o si nfa ironupiwada ati ibanujẹ oniwa-bi-Ọlọrun, ti ntipa bayi mu wa wá si ipo ẹni ti a dariji niwaju Ọlọrun.’
◻ ITUNRAPADA NIPASẸ IBAKẸGBẸ KRISTIAN: Ẹlẹkọọ-isin Roman Katoliki Boniface A. Willems (1970) mu “itunrapada” baradọgba pẹlu “yiyipada kuro ninu igbera ẹni larugẹ wa ati ṣiṣi ọkan araawa paya fun ẹnikinni ẹnikeji.” Oun fi kun un pe: “Erongba Kristian nipa ijiya afidipo tabi fun ẹlomiran ni pé ẹnikan mọ ara rẹ lati ni isopọ ninu ifohunṣọkan pẹlu ẹya iran eniyan ti ẹṣẹ ti sọ dibajẹ. . . . Nigba naa Ṣọọṣi jẹ ibakẹgbẹ awọn wọnni ti wọn ṣe tan lati gbe igbesi-aye ninu iṣe-isin akanṣe nititori awọn ẹlomiran.”
◻ ÀBÁ ERO ORI OJIYA ẸṢẸ ẸLOMIRAN: Ẹlẹkọọ-isin Katoliki Raymund Schwager dabaa eyi ni 1978. Oun ṣá ero naa tì pe Ọlọrun yoo “fi dandan beere oju fun oju.” Oun wo ẹbọ Kristi gẹgẹbi iru isọdi mímọ́ (iwẹnumọ gaara) kan ti o yọnda ẹgbẹ awujọ eniyan lati fi silẹ—ki o si tipa bayi gba ara rẹ silẹ—lọwọ awọn itẹsi oniwa ipa ti a bi mọ́ ọn.
◻ ITUNRAPADA TI ẸGBẸ-OUN-ỌGBA ATI TI OṢELU: Ẹlẹkọọ-isin Baptist Thorwald Lorenzen kọwe ni 1985 pe: “Ọlọrun ko wulẹ wá idariji nipa ti isin nikan fun ẹlẹṣẹ ṣugbọn o tun nwa itusilẹ lọna oṣelu fun awọn otoṣi ati awọn tí a ni lara. . . . Nitori naa iku Jesu ṣi Ọlọrun kan payá ti o ni idaniyan fun ṣiṣe iwosan gbogbo apa iha igbesi-aye ẹda-eniyan.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Awọn ẹlẹkọọ-isin Protestant ati Katoliki ti mu aimọye awọn àbá ero-ori nipa itunrapada ati irapada naa jade, ṣugbọn ki ni Bibeli fi kọni?