-
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
-
-
2. Kí ló pọn dandan pé kí àwọn Kristẹni ṣe ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni? Kí ló mú kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀?
2 Ó dájú pé wàá rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, èyí tí òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Lúùkù ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó ní: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:20) Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni tó tẹ̀ lé ìkìlọ̀ náà?’ Jésù tún sọ pé: “Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:21) Báwo ni wàá ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ ogun ti yí i ká? Wàyí o, ohun kan tó jẹ́ ìyàlẹ́nu ṣẹlẹ̀. Ṣàdédé lo rí i tí àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣẹ́rí pa dà kúrò ní Jerúsálẹ́mù! Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a “ké” àtakò wọn “kúrú.” (Mát. 24:22) O wá láǹfààní láti tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún ẹ. Lójú ẹsẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́ yòókù tí wọ́n wà ní ìlú náà àti àgbègbè rẹ̀ sá lọ sórí àwọn òkè tó wà ní òdìkejì Odò Jọ́dánì.a Lẹ́yìn náà, ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù míì forí lé Jerúsálẹ́mù wọ́n sì pa ìlú náà run. Àmọ́, o là á já torí pé o tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù.
-
-
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
-
-
ÀKÓKÒ ÌDÁNWÒ ÀTI ÌDÁJỌ́
7, 8. Àǹfààní wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run tó bá jẹ́ olóòótọ́ máa ní lẹ́yìn ìparun àwọn ètò ìsìn èké? Báwo ni wọ́n á ṣe dá yàtọ̀ nígbà yẹn?
7 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun gbogbo ètò ìsìn èké? Àkókò yẹn ni ohun tó wà lọ́kàn wa máa fara hàn kedere. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ààbò lọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó dà bí “àpáta orí òkè” ìyẹn àwọn àjọ tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀. (Ìṣí. 6:15-17, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa sá lọ síbi ààbò tí Jèhófà pèsè. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àkókò díẹ̀ tí àwọn Kristẹni ní láti fi sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣe àkókò láti sọ gbogbo àwọn Júù di Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkókò tí àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n sì ṣègbọràn ni. Bákan náà, a ò lè retí pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ní àkókò tí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ fi máa dáwọ́ dúró díẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn á ní àǹfààní láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin Kristi.—Mát. 25:34-40.
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìdánwò yẹn, a mọ̀ pé ó máa gba pé ká yááfì àwọn ohun kan. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni ní láti fi gbogbo ohun ìní wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fara da ọ̀pọ̀ ìnira kí wọ́n lè là á já. (Máàkù 13:15-18) Ká bàa lè jẹ́ olóòótọ́, ǹjẹ́ a ṣe tán láti pàdánù àwọn ohun ìní wa? Ṣé a máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Ẹ tiẹ̀ wo bó ṣe máa rí nígbà yẹn, bíi ti wòlíì àtijọ́ náà, Dáníẹ́lì, àwa nìkan la ó máa sin Ọlọ́run nìṣó, láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí!—Dán. 6:10, 11.
-