-
Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 15
-
-
Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sára Simeoni ó sì ti san èrè fún un nípasẹ̀ ìṣípayá. Simeoni kì yóò kú títí tí yóò fi rí Ẹni náà tí yóò jẹ́ Messia. Ṣùgbọ́n ọjọ́ àti oṣù ń kọjá lọ. Simeoni ń darúgbó èkukáká ni ó sì fi lè réti láti gbé pẹ́ síi. Ìlérí Ọlọrun fún un yóò ní ìmúṣẹ bí?
-
-
Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 15
-
-
Ẹ sì wo bí ayọ̀ tí Simeoni fi gbé ọmọ náà Jesu sí ọwọ́ rẹ̀ tí pọ̀ tó! Ẹni yìí ni yóò jẹ́ Messia náà tí a ṣèlérí—“Kristi Oluwa.” Ní irú ọjọ́ ogbó bẹ́ẹ̀, Simeoni kò lè retí láti ríi kí Jesu ṣàṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ láti rí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ kan. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Messia ti bẹ̀rẹ̀ síí ní ìmúṣẹ. Ẹ wo bí Simeoni ti láyọ̀ tó! Nísinsìnyí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn láti sùn nínú ikú títí di ìgbà àjíǹde.—Luku 2:25-28.
-