ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “kò sí ẹni tí í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ”?

      ▪ Ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa tọ́jú wáìnì sínú awọ ẹran lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. (Jóṣúà 9:13) Awọ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ bí ewúrẹ́ tàbí ti ọmọ rẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe ìgò awọ. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa ẹran náà, wọ́n á gé orí àtàwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n á wá rọra bó awọ ẹran náà kí ikùn rẹ̀ máa bàa luhò. Wọ́n á sá awọ náà, wọ́n á sì wá rán ojú àwọn ibi tí wọ́n gé náà àyàfi ọrùn tàbí ọ̀kan lára ẹsẹ̀ ẹran náà nítorí ibẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe ọrùn ìgò. Wọ́n máa ń fi nǹkan dí ojú ibi tí wọn kò rán náà tàbí kí wọ́n fi okùn so ó.

      Tó bá yá, awọ náà máa ń gan paali, kò sì ní lè fẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ògbólógbòó àpò awọ kò ní ṣeé tọ́jú wáìnì tuntun pa mọ́ sí, torí bí ọtí bá ṣe ń pẹ́ ni á máa lágbára sí i. Bó ṣe ń lágbára sí yẹn sì lè bẹ́ awọ tó ti gbó. Àmọ́ awọ tuntun ní tiẹ̀ ṣì rọ̀, wáìnì tuntun ò sì lè tètè bẹ́ ẹ. Nítorí ìdí yìí, ohun tí Jésù sọ jẹ́ òótọ́, àwọn èèyàn sì mọ̀ nípa èyí dáadáa ní ọjọ́ rẹ̀. Ó sọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ téèyàn bá fi wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó àpò awọ, ó ní: “Nígbà náà wáìnì tuntun yóò bẹ́ àwọn àpò awọ náà, yóò sì dà sílẹ̀, àwọn àpò awọ náà yóò sì bàjẹ́. Ṣùgbọ́n wáìnì tuntun ni a gbọ́dọ̀ fi sínú àwọn àpò awọ tuntun.”—Lúùkù 5:37, 38.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

      Ògbólógbòó àpò awo

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́