ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Rán 70 Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde
    Ilé Ìṣọ́—1998 | March 1
    • Jésù fun àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni síwájú sí i pé: “Ẹ má ṣe gbé àpò, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ, tàbí sálúbàtà, kí ẹ má sì gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà.” (Lúùkù 10:4) Àsùnwọ̀n àti oúnjẹ́ nìkan kọ́ ni ó jẹ́ àṣà arìnrìn àjò kan láti gbé lọ́wọ́, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ àṣà láti tún mú sálúbàtà kan tí yóò fi pààrọ̀ dání, nítorí pé ẹsẹ̀ sálúbàtà rẹ̀ lè jẹ, okùn rẹ̀ sì lè já. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ní láti ṣàníyàn nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò bójú tó wọn nípasẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn tí ṣíṣaájò àlejò jẹ́ àṣà wọn.

      Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jésù fi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti má ṣe gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra bí wọ́n bá ń kí wọn? Wọ́n ha ní láti má ṣọ̀yàyà síni, kí wọ́n tilẹ̀ má bọ̀wọ̀ fúnni? Rárá o! Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·spaʹzo·mai, tí ó túmọ̀ sí láti gbáni mọ́ra bí a bá ń kíni, lè ní ìtumọ̀ tí ó ju wíwulẹ̀ sọ pé, “ẹ ǹlẹ́ o” tàbí “ẹ kú déédéé ìwòyí o.” Ó tún lè wémọ́ àṣà fífẹnu koni lẹ́nu, gbígbánimọ́ra, àti ìjíròrò gígùn, tí ó ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ojúlùmọ̀ méjì bá pàdé. Oníròyìn kan wí pé: “Ìkíni láàárín àwọn ará Ìlà Oòrùn kì í ṣe ti títẹríba díẹ̀, tàbí bíbọnilọ́wọ́, bí ti àwa ará Ìwọ̀ Oòrùn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti gbígbánimọ́ra lọ́pọ̀ ìgbà, àti ti títẹríba dáradára, àní dídọ̀bálẹ̀ gbalaja pàápàá. Gbogbo èyí gba ọ̀pọ̀ àkókò.” (Fi wé 2 Àwọn Ọba 4:29.) Jésù tipa báyìí ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìpínyà ọkàn tí kò pọndandan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ àṣà.

  • Jésù Rán 70 Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde
    Ilé Ìṣọ́—1998 | March 1
    • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó lé ní 5,000,000 dáadáa yíká ayé, ni ó ń ṣe iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nísinsìnyí. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n mọ̀ pé ìhìn iṣẹ́ wọ́n jẹ́ kánjúkánjú. Nítorí náà, wọ́n ń lo àkókò wọn lọ́nà tí ó dára jù lọ, wọ́n ń yẹra fún àwọn ìpínyà ọkàn tí ó lè dí wọn lọ́wọ́ pípa àfiyèsí pọ̀ sórí iṣẹ́ pàtàkì tí a yàn fún wọn.

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sakun láti ṣọ̀yàyà sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá bá pàdé. Síbẹ̀, wọn kì í wulẹ̀ kó wọnú ìjíròrò tí kò ní láárí, tàbí lọ́wọ́ nínú àwọn ìjiyàn lórí àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ìkùnà ayé yìí láti mú àìsídàájọ́ òdodo kúrò. (Jòhánù 17:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjíròrò wọn dá lórí ojútùú kan ṣoṣo pípẹ́ títí fún àwọn ìṣòro ènìyàn—Ìjọba Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́