ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Èéṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | September 15
    • Nígbà yẹn, olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Jesu béèrè pé: “Ta ni ha sì ni ẹnìkejì mi?” Dípò dídáhùn tààràtà, Jesu sọ ìtàn alákàwé kan nípa ọkùnrin Ju kan tí wọ́n dá lọ́nà, tí wọ́n lù, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ ní àpaàpatán. Àwọn Ju méjì ń kọjá lọ—lákọ̀ọ́kọ́ àlùfáà kan àti lẹ́yìn náà ọmọ Lefi kan. Àwọn méjèèjì wo ipò Ju ẹlẹgbẹ́ wọ́n ṣùgbọ́n wọn kò ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́. Ará Samaria kan wá wá lẹ́yìn náà. Bí àánú ti ṣe é, ó di ojú ọgbẹ́ Ju tí a ṣálọ́gbẹ́ náà, ó mú un lọ sí ilé-èrò kan, ó sì pèsè fún àbójútó rẹ̀ síwájú síi.

      Jesu béèrè lọ́wọ́ olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ pe: “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé í ṣe ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Ní kedere, aláàánú ará Samaria náà ni. Jesu tipa báyìí fihàn pé ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ tayọ àwọn ààlà àwùjọ ẹ̀yà-ìran.—Luku 10:29-37.

  • Ìfẹ́ Aládùúgbò Ṣeéṣe
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | September 15
    • Àpẹẹrẹ Rere ti Jesu

      Àwọn Ju ọ̀rúndún kìn-ín-ní ní àwọn ìmọ̀lára alágbára lòdìsí àwọn ará Samaria, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń gbé ní àgbègbè kan láàárín Judea àti Galili. Ní àkókò kan àwọn alátakò tí wọ́n jẹ́ Ju fi tẹ̀gàntẹ̀gàn béèrè lọ́wọ́ Jesu pé: “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ í ṣe, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?” (Johannu 8:48) Èrò òdì sí àwọn ará Samaria lágbára débi pé àwọn Ju kan tilẹ̀ gégùn ún fún àwọn ará Samaria ní gbangba nínú sinagọgu tí wọ́n sì ń gbàdúrà lójoojúmọ́ pé kí àwọn ará Samaria má rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà.

      Ìmọ̀ nípa ìkórìíra tí ó fìdí múlẹ̀ yìí láìṣe àníàní ni ó sún Jesu láti sọ àkàwé nípa ará Samaria náà tí ó fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ aládùúgbò tòótọ́ nípa bíbójútó ọkùnrin Ju náà tí awọ́n ọlọ́ṣà lù. Báwo ni Jesu ìbá ti dáhùn nígbà tí ọkùnrin Ju náà tí ó mọ Òfin Mose dáradára béèrè pé: “Ta ni ha sì ni ẹnìkejì mi?” (Luku 10:29) Ó dára, Jesu ìbá ti dáhùn ní tààràtà nípa sísọ pé: ‘Àwọn aládùúgbò rẹ ní nínú kìí ṣe kìkì àwọn Ju ẹlẹgbẹ́ rẹ nìkan ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mìíràn pẹ̀lú, àní ará Samaria kan.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ìbá ti ṣòro fún àwọn Ju láti gba ìyẹn. Nítorí náà ó ṣe àkàwé nípa Ju kan tí ó rí àánú ará Samaria kan gbà. Jesu tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn Ju olùtẹ́tísílẹ̀ lọ́wọ́ láti dé ìparí-èrò náà pé ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ yóò nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn kìí ṣe Ju.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́