ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́—2015 | October 15
    • “Màríà . . . ń fetí sí ọ̀rọ̀ [Jésù]. Màtá . . . ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe.”—LÚÙKÙ 10:39, 40.

  • Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́—2015 | October 15
    • 2 Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àlejò ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Ṣùgbọ́n ohun tó mú kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ni pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára. Màtá gba àwọn ẹ̀kọ́ Jésù gbọ́ tọkàntọkàn, kò sì ṣiyè méjì pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòh. 11:21-27) Síbẹ̀, Màtá kì í ṣe ẹni pípé torí pé òun náà máa ń ṣàṣìṣe bíi ti gbogbo èèyàn. Nígbà kan tí Màtá gba Jésù lálejò, ó sọ fún Jésù pé ó yẹ kó bá Màríà wí torí pé kò bá òun ṣiṣẹ́. Màtá sọ pé: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un . . . kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.” (Ka Lúùkù 10:38-42.) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí?

  • Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́—2015 | October 15
    • 4 Àmọ́ ọkàn Màtá ò pa pọ̀, ńṣe ló ń sè tó ń sọ̀ kí ara lè tu Jésù. Gbogbo bó sì ṣe ń dá mú tibí tó ń dá mú tọ̀hún múnú bí i torí pé Màríà ò bá a dá sí i. Jésù rí i pé oúnjẹ tí Màtá ń sè ti pọ̀ jù, torí náà ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.” Ó wá sọ́ fún un pé oúnjẹ kan ṣoṣo ti tó. Àmọ́, Jésù gbóríyìn fún Màríà, ó sọ pé: “Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà lè tètè gbàgbé ohun tó jẹ lọ́jọ́ yẹn, kò jẹ́ gbàgbé bí Jésù ṣe gbóríyìn fún un àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbọ́ látẹnu rẹ̀ torí pé ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀.” (Jòh. 11:5) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Màtá gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fún un, ó sì sapá láti sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́