ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Ó Ṣe Yẹ Kí A Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | July 15
    • NÍGBÀ tí ọmọ ẹ̀yìn kán béèrè fún ìtọ́ni lórí àdúrà, Jésù kò kọ̀ láti fi fún un. Ní ìbámu pẹ̀lú Lúùkù 11:2-4, ó fèsì pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé: Bàbá, kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí awa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè. Má sì ṣe ṣamọ̀nà wá sínú ìdẹwò.” (Douay Version ti Kátólíìkì) Èyí ni ọ̀pọ́ mọ̀ sí Àdúrà Olúwa. Ó gbé ọ̀pọ̀ ìsọfúnni yọ.

  • Báwo Ni Ó Ṣe Yẹ Kí A Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | July 15
    • Ó dùn mọ́ni pé, Jésù tún fi hàn pé àdúrà wa lè ní àwọn ọ̀ràn ti ara ẹni tí ó kàn wá nínú. Ó sọ pé: “Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè. Má sì ṣe ṣamọ̀nà wa sínú ìdẹwò.” (Lúùkù 11:3, 4, Dy) Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí pé a lè béèrè fún ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú gbogbo ọ̀ràn ojoojúmọ́, pé a lè tọ Jèhófà lọ nípa ohunkóhun tí ó lè dààmú wa tàbí da àlàáfíà ọkàn wa láàmú. Bíbẹ Ọlọ́run déédéé lọ́nà yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì gbígbé tí a gbára lé e. Nípa báyìí, a túbọ̀ ń mọ ipa ìdarí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Bíbéèrè lójoojúmọ́ pé kí Ọlọ́run dárí jì wá nítorí àwọn láìfí wa ṣàǹfààní lọ́nà kan náà. A ń tipa bẹ́ẹ̀ mọ àwọn àìlera wa sí i—a sì túbọ̀ ń fara da ìkùnà àwọn ẹlòmíràn. Ìgbaniníyànjú Jésù pé kí á gbàdúrà fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ìdẹwò tún bá a mu wẹ́kú, ní pàtàkì lójú ìwòye ìwà rere ayé yìí tí ń lọ sílẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, a ń ṣọ́ra láti yẹra fún àwọn àyíká ipò àti agbègbè tí ó lè ṣamọ̀nà wa sínú ṣíṣe ohun tí kò tọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́