ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù, Ibo sì Ni Wọ́n Bí I Sí?
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì tó jẹ́ alákòóso Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. Torí náà, ó di dandan kí Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní gúúsù Jerúsálẹ́mù.

      Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù torí kí wọ́n lè forúkọ sílẹ̀. Jósẹ́fù àti Màríà ò rí ibi tí wọ́n lè dé sí, ibì kan ṣoṣo tí àyè wà ni ilé ẹran tí wọ́n máa ń kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àtàwọn ẹranko míì sí. Ibẹ̀ ni Màríà bí Jésù sí. Màríà wá fi aṣọ wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran, níbi tí wọ́n máa ń bu oúnjẹ ẹran sí.

      Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ló mú kí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣe òfin pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé òfin yẹn ló mú kí wọ́n bí Jésù sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ Ọba Dáfídì baba ńlá rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú yìí ni wọ́n máa bí Alákòóso tí Ọlọ́run ṣèlérí sí.—Míkà 5:2.

  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù, Ibo sì Ni Wọ́n Bí I Sí?
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé December 25 ni wọ́n bí Jésù. Àmọ́ ní agbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àsìkò òjò àti òtútù ni December máa ń jẹ́. Kódà, yìnyín máa ń já bọ́ nígbà míì. Nírú àsìkò yẹn, kò dájú pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa wà pẹ̀lú àwọn àgùntàn wọn nínú pápá láti alẹ́ mọ́jú. Yàtọ̀ síyẹn, kò dájú pé alákòóso Róòmù máa pàṣẹ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ forúkọ sílẹ̀ lásìkò òjò àti òtútù, tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ṣọ̀tẹ̀ sí i tẹ́lẹ̀. Torí náà, ẹ̀rí fi hàn pé nǹkan bí oṣù October ni wọ́n bí Jésù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́