ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jèhófà, Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | October 1
    • 9, 10. (a) Irú àyípadà wo ni ó dé bá ọmọ onínàákúnàá, báwo sì ni ó ṣe gbà á? (b) Ṣàpèjúwe bí àwọn kan lónìí tí wọ́n fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ ṣe ní irú ìṣòro tí ó jọ ti ọmọ onínàákúnàá?

      9 “Nígbà tí ó ti ná ohun gbogbo tán, ìyàn wá mú gan-an jákèjádò ilẹ̀ yẹn, ó sì wá wà nínú àìní. Ó tilẹ̀ lọ so ara rẹ̀ mọ́ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú ilẹ̀ yẹn, ó sì rán an sínú àwọn pápá rẹ̀ láti máa ṣe olùṣọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Òun a sì máa fẹ́ láti jẹ àwọn pódi èso kárọ́ọ̀bù ní àjẹyó, èyí tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, kò sì sí ẹni tí yóò fún un ní ohunkóhun.”—Lúùkù 15:14-16.

  • “Jèhófà, Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | October 1
    • 11. Kí ni ó mú kí ìṣòro ọmọ onínàákúnàá peléke sí i, báwo sì ni àwọn kan lónìí ṣe wá rí i pé “ẹ̀tàn òfifo” gbáà ni gbogbo nǹkan yòyòòyò ti ayé?

      11 Ìṣòro ọmọ onínàákúnàá náà tún wá peléke sí i nítorí pé “kò . . . sí ẹni tí yóò fún un ní ohunkóhun.” Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tuntun tó ń kó kiri ńkọ́? Nísinsìnyí tí kò ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́ mọ́, ó wá dà bí “ẹni ìkórìíra” sí wọn. (Òwe 14:20) Bákan náà, ọ̀pọ̀ lónìí tí wọ́n ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ́ wá rí i pé “ẹ̀tàn òfìfo” gbáà ni gbogbo nǹkan yòyòòyò ti ayé yìí àti ojú ìwòye rẹ̀. (Kólósè 2:8) Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí ó ti fi ètò àjọ Ọlọ́run sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ sọ pé: “Mo jẹ baba ńlá ìyà, ìrora ọkàn sì bá mi nítorí àìní ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Mo gbìyànjú láti ṣe bí ayé ti ń ṣe, ṣùgbọ́n nítorí pé ìwà mi kò jọ tiwọn délẹ̀délẹ̀, wọ́n kọ̀ mí. Mo wá dà bí ọmọ tí ó sọnù tí ó nílò baba rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà. Ìgbà yẹn ni mo tó wá mọ̀ pé mo nílò Jèhófà. N kò tún fẹ́ máa gbé ayé mọ́ láìgbára lé e.” Ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù pẹ̀lú wá mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́