ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jèhófà, Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | October 1
    • 12, 13. Kí ni àwọn nǹkan tí ó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ lónìí láti pe orí ara wọn wálé? (Wo àpótí.)

      12 “Nígbà tí orí rẹ̀ wálé, ó wí pé, ‘Mélòómélòó ni àwọn ọkùnrin tí baba mi háyà, tí wọ́n ní oúnjẹ púpọ̀ gidigidi, nígbà tí èmi ń ṣègbé lọ níhìn-ín lọ́wọ́ ìyàn! Ṣe ni èmi yóò dìde, n ó sì rin ìrìn àjò lọ sọ́dọ̀ baba mi, n ó sì wí fún un pé: “Baba, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ. Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.”’ Nítorí náà, ó dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ baba rẹ̀.”—Lúùkù 15:17-20.

  • “Jèhófà, Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | October 1
    • 14. Ìpinnu wo ni ọmọ onínàákúnàá náà ṣe, báwo sì ni ó ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀?

      14 Ṣùgbọ́n kí ni àwọn tí wọ́n ti ṣáko lọ lè ṣe nípa ipò wọn? Nínú àkàwé Jésù, ọmọ onínàákúnàá náà pinnu láti rìnrìn àjò padà sílé, kí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì baba rẹ̀. Ọmọ onínàákúnàá náà pinnu láti sọ pé: “Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.” Iṣẹ́ òòjọ́ ni a ń gba ìránṣẹ́ kan tí a háyà fún, ìsọfúnni ọjọ́ kan péré sì ti tó láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ipò rẹ̀ tilẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju ti ẹrú lọ, ẹni tí ó jẹ́ pé, lọ́nà kan, ojú mẹ́ńbà ìdílé lá fi ń wò ó. Nítorí náà, ọmọ onínàákúnàá náà kò ní in lọ́kàn pé kí a padà fi òun sí ipò ọmọ tí òun wà tẹ́lẹ̀. Kíá ni yóò gbà láti wà ní ipò rírẹlẹ̀ jù lọ yìí, kí ó lè fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ tí ó sọ dọ̀tun hàn fún baba rẹ̀ lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n, ẹnu yóò ya ọmọ onínàákúnàá náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́